Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 13:10-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ninu ẹ̀ya Sebuluni, Gaddieli ọmọ Sodi.

11. Ninu ẹ̀ya Josefu, eyinì ni, ninu ẹ̀ya Manasse, Gadi ọmọ Susi.

12. Ninu ẹ̀ya Dani, Ammieli ọmọ Gemalli.

13. Ninu ẹ̀ya Aṣeri, Seturu ọmọ Mikaeli.

14. Ninu ẹ̀ya Naftali, Nabi ọmọ Fofsi.

15. Ninu ẹ̀ya Gaddi, Geueli ọmọ Maki.

16. Wọnyi li orukọ awọn ọkunrin na, ti Mose rán lati lọ ṣe amí ilẹ na. Mose si sọ Oṣea ọmọ Nuni ni Joṣua.

17. Mose si rán wọn lọ ṣe amí ilẹ Kenaani, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbà ọ̀na ìha gusù yi, ki ẹ sì lọ sori òke nì.

18. Ki ẹnyin si wò ilẹ na, bi o ti ri; ati awọn enia ti ngbé inu rẹ̀, bi nwọn ṣe alagbara tabi alailagbara, bi diẹ ni nwọn, tabi pupọ̀;

19. Ati bi ilẹ na ti nwọn ngbé ti ri, bi didara ni bi buburu ni; ati bi ilu ti nwọn ngbé ti ri, bi ninu agọ́ ni, tabi ninu ilu odi;

20. Ati bi ilẹ na ti ri, bi ẹlẹtu ni tabi bi aṣalẹ̀, bi igi ba mbẹ ninu rẹ̀, tabi kò sí. Ki ẹnyin ki o si mu ọkàn le, ki ẹnyin si mú ninu eso ilẹ na wá. Njẹ ìgba na jẹ́ akokò pipọn akọ́so àjara.

21. Bẹ̃ni nwọn gòke lọ, nwọn si ṣe amí ilẹ na lati ijù Sini lọ dé Rehobu, ati lọ si Hamati.

22. Nwọn si ti ìha gusù gòke lọ, nwọn si dé Hebroni; nibiti Ahimani, Ṣeṣai, ati Talmai, awọn ọmọ Anaki gbé wà. (A ti tẹ̀ Hebroni dò li ọdún meje ṣaju Soani ni Egipti.)

23. Nwọn si dé odò Eṣkolu, nwọn si rẹ́ ọwọ́ àjara kan, ti on ti ìdi eso-àjara kan lati ibẹ̀ wá, awọn enia meji si fi ọpá rù u; nwọn si mú ninu eso-pomegranate, ati ti ọpọtọ́ wá.

24. Nwọn si sọ ibẹ̀ na ni odò Eṣkolu, nitori ìdi-eso ti awọn ọmọ Israeli rẹ́ lati ibẹ̀ wá.

Ka pipe ipin Num 13