Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Neh 9:26-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Ṣugbọn nwọn ṣe alaigbọràn, nwọn si ṣọ̀tẹ si ọ, nwọn si gbe ofin rẹ sọ si ẹ̀hin wọn, nwọn si pa awọn woli rẹ ti nsọ fun wọn lati yipada si ọ, nwọn si ṣe imunibinu nla.

27. Nitorina ni iwọ fi wọn le ọwọ awọn ọta wọn, ti o pọn wọn loju, ati li akoko ipọnju wọn, nigbati nwọn kigbe pè ọ, iwọ gbọ́ lati ọrun wá; ati gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ, iwọ fun wọn li olugbala, ti nwọn gbà wọn kuro lọwọ awọn ọta wọn.

28. Ṣugbọn li ẹhin ti nwọn ni isimi, nwọn si tun ṣe buburu niwaju rẹ: nitorina ni iwọ fi wọn le ọwọ awọn ọta wọn, tobẹ̃ ti nwọn jọba li ori wọn: ṣugbọn nigbati nwọn pada, ti nwọn si kigbe pè ọ, iwọ gbọ́ lati ọrun wá, ọ̀pọlọpọ ìgba ni iwọ si gbà wọn gẹgẹ bi ãnu rẹ.

29. Iwọ si jẹri gbè wọn ki iwọ ki o le tun mu wọn wá sinu ofin rẹ, ṣugbọn nwọn hu ìwa igberaga, nwọn kò si fi eti si ofin rẹ, nwọn si ṣẹ̀ si idajọ rẹ (eyiti bi enia ba ṣe on o yè ninu wọn), nwọn si gún èjika, nwọn mu ọrùn wọn le, nwọn kò si fẹ igbọ́.

30. Sibẹ ọ̀pọlọpọ ọdun ni iwọ fi mu suru fun wọn ti o si fi ẹmi rẹ jẹri gbè wọn ninu awọn woli rẹ: sibẹ̀ nwọn kò fi eti silẹ: nitorina ni iwọ ṣe fi wọn le ọwọ awọn enia ilẹ wọnni.

31. Ṣugbọn nitori ãnu rẹ nla iwọ kò run wọn patapata, bẹ̃ni iwọ kò kọ̀ wọn silẹ; nitori iwọ li Ọlọrun olore-ọfẹ ati alãnu.

32. Njẹ nitorina, Ọlọrun wa, Ọlọrun ti o tobi, ti o li agbara, ti o si li ẹ̀ru, ẹniti npa majẹmu ati ãnu mọ, má jẹ ki gbogbo iyọnu na dabi ohun kekere niwaju rẹ, o de bá wa, awọn ọba wa, awọn ijoye wa, ati awọn alufa wa, ati awọn woli wa, ati awọn baba wa, ati gbogbo awọn enia rẹ lati akoko ọba Assiria wá, titi o fi di oni yi.

33. Sibẹ, iwọ ṣe olododo ninu ohun gbogbo ti o de ba wa, iwọ si ti ṣe otitọ, ṣugbọn awa ti ṣe buburu:

34. Awọn ọba wa, awọn ijoye wa, awọn alufa wa, ati awọn baba wa, kò pa ofin rẹ mọ, bẹ̃ni nwọn kò fi eti si aṣẹ rẹ, ati ẹri rẹ, ti iwọ fi jẹri gbè wọn.

35. Nitori ti nwọn kò sin ọ ninu ijọba wọn, ati ninu ore rẹ nla ti iwọ fi fun wọn, ati ninu ilẹ nla ati ọlọra ti o fi si iwaju wọn, bẹ̃ni nwọn kò pada kuro ninu iṣẹ buburu wọn.

36. Kiyesi i, ẹrú li awa iṣe li oni yi, ati ilẹ ti iwọ fi fun awọn baba wa lati ma jẹ eso rẹ̀, ati ire rẹ̀, kiyesi i, awa jẹ ẹrú ninu rẹ̀.

37. Ilẹ na si mu ohun ọ̀pọlọpọ wá fun awọn ọba, ti iwọ ti fi ṣe olori wa nitori ẹ̀ṣẹ wa: nwọn ni aṣẹ lori ara wa pẹlu, ati lori ẹran-nla wa, bi o ti wù wọn, awa si wà ninu wàhala nla.

38. Ati nitori gbogbo eyi awa dá majẹmu ti o daju, a si kọwe rẹ̀; awọn ìjoye wa, awọn ọmọ Lefi, ati awọn alufa si fi èdidi di i.

Ka pipe ipin Neh 9