Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Neh 9:12-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Iwọ si fi ọwọ̀n awọ-sanma ṣe amọ̀na wọn li ọsan, ati li oru, ọwọ̀n iná, lati fun wọn ni imọlẹ li ọ̀na ninu eyiti nwọn o rin.

13. Iwọ si sọkalẹ wá si ori òke Sinai, o si bá wọn sọ̀rọ lati ọrun wá, o fun wọn ni idajọ titọ, ofin otitọ, ilana ati ofin rere.

14. Iwọ si mu ọjọ isimi mimọ rẹ di mimọ̀ fun wọn, o si paṣẹ ẹkọ́, ilana, ati ofin fun wọn, nipa ọwọ Mose iranṣẹ rẹ.

15. O si fun wọn li onjẹ lati ọrun wá fun ebi wọn, o si mu omi lati inu apata wá fun orungbẹ wọn, o si ṣe ileri fun wọn pe, ki nwọn lọ ijogun ilẹ na ti iwọ ti bura lati fi fun wọn.

16. Ṣugbọn awọn ati awọn baba wa hu ìwa igberaga, nwọn si mu ọrùn wọn le, nwọn kò si gba ofin rẹ gbọ́.

17. Nwọn si kọ̀ lati gbọràn, bẹ̃ni nwọn kò ranti iṣẹ iyanu ti iwọ ṣe li ãrin wọn; ṣugbọn nwọn mu ọrùn wọn le, ninu ìṣọtẹ wọn, nwọn yan olori lati pada si oko-ẹrú wọn: ṣugbọn iwọ li Ọlọrun ti o mura lati dariji, olore ọfẹ, ati alãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pipọ̀, o kò si kọ̀ wọn silẹ.

18. Nitõtọ nigbati nwọn ṣe ẹgbọrọ-malu didà, ti nwọn si wipe, Eyi li Ọlọrun rẹ ti o mu ọ gòke ti Egipti jade wá, nwọn si ṣe imunibinu nla.

19. Ṣugbọn iwọ, ninu ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ, kò kọ̀ wọn silẹ li aginju, ọwọ̀n kũkũ kò kuro lọdọ wọn lojojumọ lati ṣe amọna wọn, bẹ̃ si li ọwọ̀n iná lati fun wọn ni imọlẹ li oru li ọ̀na ti nwọn iba rìn.

20. Iwọ fun wọn li ẹmi rere rẹ pẹlu lati kọ́ wọn, iwọ kò si gba manna rẹ kuro li ẹnu wọn, iwọ si fun wọn li omi fun orungbẹ wọn.

21. Nitotọ, ogoji ọdun ni iwọ fi bọ́ wọn li aginju, nwọn kò si ṣe alaini; aṣọ wọn kò gbó, ẹsẹ wọn kò si wú.

Ka pipe ipin Neh 9