Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Neh 9:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọjọ kẹrinlelogun oṣu yi, awọn ọmọ Israeli pejọ ninu àwẹ ati aṣọ ọ̀fọ, ati erupẹ lori wọn.

2. Awọn iru-ọmọ Israeli si ya ara wọn kuro ninu awọn ọmọ alejo, nwọn si duro, nwọn jẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn, ati aiṣedede awọn baba wọn.

3. Nwọn si dide duro ni ipò wọn, nwọn si fi idamẹrin ọjọ kà ninu iwe ofin Oluwa Ọlọrun wọn; nwọn si fi idamẹrin jẹwọ, nwọn si sìn Oluwa Ọlọrun wọn.

4. Nigbana ni Jeṣua, ati Bani, Kadmieli, Ṣebaniah, Bunni, Ṣerebiah, Bani ati Kenani duro lori pẹtẹsì awọn ọmọ Lefi, nwọn si fi ohun rara kigbe si Oluwa Ọlọrun wọn.

5. Awọn ọmọ Lefi, Jeṣua, Kadmieli, Bani, Haṣabaiah, Ṣerebiah, Hodijah, Sebaniah, ati Pelaniah, si wipe: Ẹ dide, ki ẹ fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun nyin lai ati lailai: ibukun si ni fun orukọ rẹ ti o li ogo, ti o ga jù gbogbo ibukun ati iyìn lọ.

6. Iwọ, ani iwọ nikanṣoṣo li Oluwa; iwọ li o ti dá ọrun, ọrun awọn ọrun pẹlu gbogbo ogun wọn, aiye, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ̀ ninu rẹ̀, iwọ si pa gbogbo wọn mọ́ lãyè, ogun ọrun si nsìn ọ.

7. Iwọ ni Oluwa Ọlọrun, ti o ti yan Abramu, ti o si mu u jade lati Uri ti Kaldea wá, iwọ si sọ orukọ rẹ̀ ni Abrahamu;

Ka pipe ipin Neh 9