Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Neh 3:20-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Lẹhin rẹ̀ ni Baruku ọmọ Sabbai fi itara tun apa miran ṣe, lati igun ogiri titi de ilẹkùn ile Eliaṣibu, olori alufa.

21. Lẹhin rẹ̀ ni Meremoti ọmọ Urijah, ọmọ Kosi tun apa miran ṣe lati ilẹkùn ile Eliaṣibu titi de ipẹkun ile Eliaṣibu.

22. Lẹhin rẹ̀ ni awọn alufa si tun ṣe, awọn ọkunrin pẹtẹlẹ [Jordani].

23. Lẹhin wọn ni Benjamini ati Haṣubu tun ṣe li ọkánkán ile wọn. Lẹhin wọn ni Asariah ọmọ Maasiah ọmọ Ananiah tun ṣe lẹba ile rẹ̀.

24. Lẹhin rẹ̀ ni Binnui, ọmọ Henadadi tun apa miran ṣe, lati ile Asariah titi de igun odi, ani titi de kọrọ̀.

25. Palali ọmọ Usai li ọkánkán igun odi, ati ile-iṣọ ti o yọ sode lati ile giga ti ọba wá ti o wà lẹba ile tubu. Lẹhin rẹ̀ ni Padaiah ọmọ Paroṣi.

26. Ṣugbọn awọn Netinimu gbe Ofeli, titi de ọkánkán ẹnu-bode omi niha ila-õrùn ati ile iṣọ ti o yọ sode.

27. Lẹhin wọn ni awọn ara Tekoa tun apa miran ṣe, li ọkánkán ile-iṣọ nla ti o yọ sode, titi de odi Ofeli.

28. Lati oke ẹnu-bode ẹṣin ni awọn alufa tun apa miran ṣe, olukuluku li ọkánkán ile rẹ̀.

29. Lẹhin wọn ni Sadoku, ọmọ Immeri tun ṣe li ọkánkán ile rẹ̀: lẹhin rẹ̀ ni Ṣemaiah ọmọ Ṣekaniah, olùtọju ẹnubode ila-õrùn tun ṣe.

30. Lẹhin wọn ni Hananiah ọmọ Selamiah tun ṣe, ati Hanuni ọmọ Salafu kẹfa tun apa miran ṣe. Lẹhin rẹ̀ ni Meṣullamu, ọmọ Berekiah li ọkánkán yàra rẹ̀.

31. Lẹhin rẹ̀ ni Malkiah ọmọ alagbẹdẹ wura tun ṣe, titi de ile awọn Netinimu ati ti awọn oniṣòwo, li ọkánkán ẹnu bode Mifkadi ati yàra òke igun-odi.

32. Ati larin yàra òke igun-odi titi de ẹnu-bode agutan ni awọn alagbẹdẹ wura ati awọn oniṣòwo tun ṣe.

Ka pipe ipin Neh 3