Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Neh 12:37-47 Yorùbá Bibeli (YCE)

37. Ati ni ẹnu-bode orisun eyi ni ibi ti o kọju si i, nwọn ba àtẹgun ilu Dafidi goke lọ, ni ibi odi ti o goke lọ, ni ikọja ile Dafidi, titi de ẹnu-bode omi, niha ila õrùn.

38. Ati ẹgbẹ keji awọn ti ndupẹ, lọ li odi keji si wọn, ati emi lẹhin wọn, pẹlu idaji awọn enia lori odi, lati ikọja ile iṣọ ileru, titi de odi gbigboro.

39. Nwọn si rekọja oke ẹnu-bode Efraimu wá, ati lati oke ẹnu-bode lailai ati li oke ẹnu-bode ẹja, ati ile-iṣọ Hananieli, ati ile-iṣọ Mea, titi de ẹnu-bode agutan, nwọn si duro li ẹnu-bode tubu.

40. Bayi ni awọn ẹgbẹ meji ti ndupẹ ninu ile Ọlọrun duro, ati emi ati idaji awọn ijoye pẹlu mi.

41. Ati awọn alufa: Eliakimu, Maaseiah, Miniamini Mikaiah, Elioenai, Sekariah, Hananiah mu fère lọwọ;

42. Ati Maaseiah, ati Ṣemaiah, ati Eleasari, ati Ussi, ati Jehohanani, ati Malkijah, ati Elamu, ati Eseri, awọn akọrin kọrin soke, pẹlu Jesrahiah alabojuto.

43. Li ọjọ na pẹlu nwọn ṣe irubọ nla, nwọn si yọ̀ nitori Ọlọrun ti mu wọn yọ̀ ayọ̀ nla, aya wọn ati awọn ọmọde yọ̀ pẹlu, tobẹ̃ ti a si gbọ́ ayọ̀ Jerusalemu li okere reré.

44. Li akoko na li a si yàn awọn kan ṣe olori yara iṣura, fun ọrẹ-ẹbọ, fun akọso, ati fun idamẹwa, lati ma ko ipin ti a yàn jọ lati oko ilu wọnni wá, ti ofin fun awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi: nitoriti Juda yọ̀ fun awọn ọmọ Lefi ti o duro.

45. Ati awọn akọrin, ati adèna npa ẹṣọ Ọlọrun wọn mọ, ati ẹṣọ iwẹnumọ́, gẹgẹ bi aṣẹ Dafidi; ati ti Solomoni ọmọ rẹ̀.

46. Nitori li ọjọ Dafidi ati Asafu nigbani awọn olori awọn akọrin wà, ati orin iyìn, ati ọpẹ fun Ọlọrun.

47. Gbogbo Israeli li ọjọ Serubbabeli, ati li ọjọ Nehemiah si fi ipin awọn akọrin, ati ti awọn adèna fun wọn olukuluku ni ipin tirẹ̀ li ojojumọ, nwọn si ya ohun mimọ́ awọn ọmọ Lefi si ọ̀tọ, awọn ọmọ Lefi si yà wọn si ọ̀tọ fun awọn ọmọ Aaroni.

Ka pipe ipin Neh 12