Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Neh 12:27-42 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Ati nigba yiya odi Jerusalemu si mimọ́, nwọn wá awọn ọmọ Lefi kiri ninu gbogbo ibugbe wọn, lati mu wọn wá si Jerusalemu lati fi ayọ̀ ṣe iyà si mimọ́ na pẹlu idupẹ ati orin, pẹlu simbali, psalteri, ati pẹlu dùru.

28. Awọn ọmọ awọn akọrin si ko ara wọn jọ lati pẹ̀tẹlẹ yi Jerusalemu ka, ati lati ileto Netofati wá;

29. Lati ile Gilgali wá pẹlu, ati lati inu ilẹ Geba ati Asmafeti, nitori awọn akọrin ti kọ ileto fun ara wọn yi Jerusalemu kakiri.

30. Ati awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi wẹ̀ ara wọn mọ́, nwọn si wẹ̀ awọn enia mọ́, ati ẹnu-bode, ati odi.

31. Nigbana ni mo mu awọn ijoye Juda wá si ori odi, mo si yàn ẹgbẹ nla meji, ninu awọn ti ndupẹ, ẹgbẹ kan lọ si apa ọtun li ori odi, siha ẹnu-bode àtan.

32. Hoṣaiah si lọ tẹle wọn ati idaji awọn ijoye Juda.

33. Ati Asariah, Esra, ati Meṣullamu,

34. Juda, ati Benjamini, ati Ṣemaiah ati Jeremiah.

35. Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa mu fère lọwọ, Sekariah, ọmọ Jonatani, ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Mattaniah, ọmọ Mikaiah, ọmọ Sakkuri, ọmọ Asafu:

36. Ati awọn arakunrin rẹ̀, Ṣemaiah, ati Asaraeli, Milalai, Gilalai, Maai, Netaneeli, ati Juda, Hanani, pẹlu ohun èlo orin Dafidi, enia Ọlọrun, ati Esra akọwe niwaju wọn.

37. Ati ni ẹnu-bode orisun eyi ni ibi ti o kọju si i, nwọn ba àtẹgun ilu Dafidi goke lọ, ni ibi odi ti o goke lọ, ni ikọja ile Dafidi, titi de ẹnu-bode omi, niha ila õrùn.

38. Ati ẹgbẹ keji awọn ti ndupẹ, lọ li odi keji si wọn, ati emi lẹhin wọn, pẹlu idaji awọn enia lori odi, lati ikọja ile iṣọ ileru, titi de odi gbigboro.

39. Nwọn si rekọja oke ẹnu-bode Efraimu wá, ati lati oke ẹnu-bode lailai ati li oke ẹnu-bode ẹja, ati ile-iṣọ Hananieli, ati ile-iṣọ Mea, titi de ẹnu-bode agutan, nwọn si duro li ẹnu-bode tubu.

40. Bayi ni awọn ẹgbẹ meji ti ndupẹ ninu ile Ọlọrun duro, ati emi ati idaji awọn ijoye pẹlu mi.

41. Ati awọn alufa: Eliakimu, Maaseiah, Miniamini Mikaiah, Elioenai, Sekariah, Hananiah mu fère lọwọ;

42. Ati Maaseiah, ati Ṣemaiah, ati Eleasari, ati Ussi, ati Jehohanani, ati Malkijah, ati Elamu, ati Eseri, awọn akọrin kọrin soke, pẹlu Jesrahiah alabojuto.

Ka pipe ipin Neh 12