Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mal 1:10-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ta si ni ninu nyin ti yio se ilẹkun? bẹ̃li ẹnyin kò da iná asan lori pẹpẹ mi mọ. Emi kò ni inu-didùn si nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, bẹ̃li emi kì yio gba ọrẹ kan lọwọ nyin.

11. Nitori lati ilã-õrùn titi o si fi de iwọ̀ rẹ̀, orukọ mi yio tobi lãrin awọn keferi; nibi gbogbo li a o si fi turàri jona si orukọ mi, pẹlu ọrẹ mimọ́: nitori orukọ mi o tobi lãrin awọn keferi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

12. Nitori ẹnyin ti sọ ọ di aimọ́, ninu eyi ti ẹ wipe, Tabili Oluwa di aimọ́; ati eso rẹ̀, ani onjẹ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gan.

13. Ẹnyin wi pẹlu pe, Wo o agara kili eyi! ẹnyin ṣitìmú si i, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; ẹnyin si mu eyi ti o ya, ati arọ, ati olokunrùn wá; bayi li ẹnyin mu ọrẹ wá: emi o ha gbà eyi lọwọ nyin? li Oluwa wi.

14. Ṣugbọn ifibu ni fun ẹlẹtàn na, ti o ni akọ ninu ọwọ́-ẹran rẹ̀, ti o si ṣe ileri ti o si fi ohun abùku rubọ si Oluwa; nitori Ọba nla li emi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ẹ̀ru si li orukọ mi lãrin awọn keferi.

Ka pipe ipin Mal 1