Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 5:3-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Tabi bi o ba farakàn ohun aimọ́ ti enia, ohunkohun aimọ́ ti o wù ki o ṣe ti a fi sọ enia di elẽri, ti o ba si pamọ́ fun u; nigbati o ba mọ̀, nigbana ni on yio jẹbi:

4. Tabi bi ẹnikan ba bura, ti o nfi ète rẹ̀ sọ ati ṣe ibi, tabi ati ṣe rere, ohunkohun ti o wù ki o ṣe ti enia ba fi ibura sọ, ti o ba si pamọ́ fun u; nigbati o ba mọ̀, nigbana ni on yio jẹbi ọkan ninu ohun wọnyi:

5. Yio si ṣe, nigbati o ba jẹbi ọkan ninu ohun wọnyi, ki o jẹwọ pe on ti ṣẹ̀ li ohun na.

6. Ki o si mú ẹbọ ẹbi rẹ̀ wá fun OLUWA, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, abo lati inu agbo-ẹran wá, ọdọ-agutan tabi ọmọ ewurẹ kan, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

7. Bi kò ba si le mú ọdọ-agutan wá, njẹ ki o mú àdaba meji tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá fun ẹbọ ẹbi fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o ti ṣẹ̀; ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun.

8. Ki o si mú wọn tọ̀ alufa wá, ẹniti yio tète rubọ eyiti iṣe ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti yio si mi i li ọrùn, ṣugbọn ki yio pín i meji:

9. Ki o si fi ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì wọ́n ìha pẹpẹ; ati ẹ̀jẹ iyokù ni ki a ro si isalẹ pẹpẹ na: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.

10. Ki o si ru ekeji li ẹbọ sisun, gẹgẹ bi ìlana na: ki alufa ki o si ṣètutu fun u, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, a o si dari rẹ̀ jì i.

11. Ṣugbọn bi on kò ba le mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá, njẹ ki ẹniti o ṣẹ̀ na ki o mú idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun daradara wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ki o máṣe fi oróro si i, bẹ̃ni ki o máṣe fi turari sori rẹ̀: nitoripe ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.

12. Nigbana ni ki o mú u tọ̀ alufa wá, ki alufa ki o si bù ikunwọ rẹ̀ kan ninu rẹ̀, ani ẹbọ-iranti rẹ̀, ki o si sun u lori pẹpẹ na, gẹgẹ bi ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.

Ka pipe ipin Lef 5