Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 4:26-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Ki o si sun gbogbo ọrá rẹ̀ li ori pẹpẹ, bi ti ọrá ẹbọ alafia: ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, a o si dari rẹ̀ jì i.

27. Bi ọkan ninu awọn enia ilẹ na ba fi aimọ̀ sẹ̀, nigbati o ba ṣì ohun kan ṣe si ọkan ninu ofin OLUWA ti a ki ba ṣe, ti o si jẹbi;

28. Tabi bi ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o ti ṣẹ̀, ba di mimọ̀ fun u, nigbana ni ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ọmọ ewurẹ kan, abo alailabùku, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀.

29. Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ na ni ibi ẹbọsisun.

30. Ki alufa ki o si fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ ẹbọsisun, ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ rẹ̀ si isalẹ pẹpẹ.

31. Ki o si mú gbogbo ọrá rẹ̀ kuro, bi a ti imú ọrá kuro ninu ẹbọ ọrẹ-ẹbọ alafia; ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ fun õrùn didùn si OLUWA; ki alufa na ki o si ṣètutu fun u, a o si dari rẹ̀ jì i.

32. Bi o ba si mú ọdọ-agutan kan wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ki o si mú u wá, abo alailabùku.

33. Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si pa a fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni ibi ti nwọn gbé npa ẹbọ sisun.

34. Ki alufa ki o si fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ ẹbọsisun, ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ rẹ̀ si isalẹ pẹpẹ:

Ka pipe ipin Lef 4