Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 3:9-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Ki o si múwa ninu ẹbọ alafia nì, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá rẹ̀, ati gbogbo ìru rẹ̀ ti o lọrá, on ni ki o mú kuro sunmọ egungun ẹhin; ati ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun,

10. Ati iwe mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro.

11. Ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ: onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA ni.

12. Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ewurẹ, njẹ ki o mú u wá siwaju OLUWA:

13. Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori rẹ̀, ki o si pa a niwaju agọ́ ajọ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká.

14. Ki o si mú ninu ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti o mbẹ lara ifun,

15. Ati iwe nì mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro.

16. Ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ: onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe fun õrùn didùn ni: ti OLUWA ni gbogbo ọrá.

17. Ìlana titilai ni fun irandiran nyin, ni gbogbo ibugbé nyin, pe ki ẹnyin ki o máṣe jẹ ọrá tabi ẹ̀jẹ.

Ka pipe ipin Lef 3