orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 3 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ẹbọ Alaafia

1. BI ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ẹbọ alafia, bi o ba mú u lati inu ọwọ́-ẹran wá, on iba ṣe akọ tabi abo, ki o mú u wá siwaju OLUWA li ailabùku.

2. Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, ki o si pa a li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: ki awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ nì yiká.

3. Ki o si mú ninu ẹbọ alafia nì wá, ọrẹ-ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun na.

4. Ati iwe nì mejeji, ati ọrá ti mbẹ́ lara wọn, ti mbẹ li ẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro.

5. Ki awọn ọmọ Aaroni ki o si sun u lori pẹpẹ nì lori ẹbọ sisun, ti mbẹ lori igi ti o wà lori iná: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni, õrùn didùn si OLUWA.

6. Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ fun ọrẹ-ẹbọ alafia si OLUWA ba ṣe ti agbo-ẹran; akọ tabi abo, ki o mú u wá li ailabùku.

7. Bi o ba mu ọdọ-agutan wá fun ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, njẹ ki o mú u wá siwaju OLUWA:

8. Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, ki o si pa a niwaju agọ́ ajọ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká.

9. Ki o si múwa ninu ẹbọ alafia nì, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá rẹ̀, ati gbogbo ìru rẹ̀ ti o lọrá, on ni ki o mú kuro sunmọ egungun ẹhin; ati ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun,

10. Ati iwe mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro.

11. Ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ: onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA ni.

12. Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ewurẹ, njẹ ki o mú u wá siwaju OLUWA:

13. Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori rẹ̀, ki o si pa a niwaju agọ́ ajọ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká.

14. Ki o si mú ninu ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti o mbẹ lara ifun,

15. Ati iwe nì mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro.

16. Ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ: onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe fun õrùn didùn ni: ti OLUWA ni gbogbo ọrá.

17. Ìlana titilai ni fun irandiran nyin, ni gbogbo ibugbé nyin, pe ki ẹnyin ki o máṣe jẹ ọrá tabi ẹ̀jẹ.