orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 15 Yorùbá Bibeli (YCE)

Àwọn Ohun Àìmọ́ tí Ń Jáde Lára

1. OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,

2. Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnikan ba ní àrun isun lara rẹ̀, nitori isun rẹ̀ alaimọ́ li on.

3. Eyi ni yio si jẹ́ aimọ́ rẹ̀ ninu isun rẹ̀: ara rẹ̀ iba ma sun isun rẹ̀, tabi bi ara rẹ̀ si dá kuro ninu isun rẹ̀, aimọ́ rẹ̀ ni iṣe.

4. Gbogbo ori akete ti ẹniti o ní isun na ba dubulẹ lé, aimọ́ ni: ati gbogbo ohun ti o joko lé yio jẹ́ alaimọ́.

5. Ẹnikẹni ti o ba farakàn akete rẹ̀ ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

6. Ẹniti o si joko lé ohunkohun ti ẹniti o ní isun ti joko lé, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

7. Ẹniti o si farakàn ara ẹniti o ní isun, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

8. Bi ẹniti o ní isun ba tutọ sara ẹniti o mọ́; nigbana ni ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

9. Ati asákasá ti o wù ki ẹniti o ní isun ki o gùn ki o jẹ́ alaimọ́.

10. Ẹnikẹni ti o ba farakàn ohun kan ti o wà nisalẹ rẹ̀, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: ati ẹniti o rù ohun kan ninu nkan wọnni, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

11. Ati ẹnikẹni ti ẹniti o ní isun ba farakàn, ti kò ti wẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ ninu omi, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

12. Ati ohunèlo amọ̀, ti ẹniti o ní isun ba fọwọkàn, fifọ́ ni ki a fọ́ ọ: ati gbogbo ohunèlo igi ni ki a ṣàn ninu omi.

13. Nigbati ẹniti o ní isun ba si di mimọ́ kuro ninu isun rẹ̀, nigbana ni ki o kà ijọ́ meje fun ara rẹ̀, fun isọdimimọ́ rẹ̀, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi ti nṣàn, yio si jẹ́ mimọ́.

14. Ati ni ijọ́ kẹjọ, ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji fun ara rẹ̀, ki o si wá siwaju OLUWA si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki o si fi wọn fun alufa:

15. Ki alufa ki o si fi wọn rubọ, ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun; ki alufa ki o si ṣètutu fun u niwaju OLUWA nitori isun rẹ̀.

16. Ati bi ohun irú ìdapọ ọkunrin ba ti ara rẹ̀ jade, nigbana ni ki o wẹ̀ gbogbo ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

17. Ati gbogbo aṣọ, ati gbogbo awọ, lara eyiti ohun irú ìdapọ ba wà, on ni ki a fi omi fọ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

18. Ati obinrin na, ẹniti ọkunrin ba bá dàpọ ti on ti ohun irú ìdapọ, ki awọn mejeji ki o wẹ̀ ninu omi, ki nwọn ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

19. Bi obinrin kan ba si ní isun, ti isun rẹ̀ li ara rẹ̀ ba jasi ẹ̀jẹ, ki a yà a sapakan ni ijọ́ meje: ẹnikẹni ti o ba si farakàn a, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

20. Ati ohun gbogbo ti o dubulẹ lé ninu ile ìyasapakan rẹ̀ yio jẹ́ aimọ́: ohunkohun pẹlu ti o joko lé yio jẹ́ aimọ́.

21. Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn akete rẹ̀, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

22. Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn ohun kan ti o joko lé, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

23. Bi o ba si ṣepe lara akete rẹ̀ ni, tabi lara ohun ti o joko lé, nigbati o ba farakàn a, ki on ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

24. Bi ọkunrin kan ba si bá a dàpọ rára, ti ohun obinrin rẹ̀ ba mbẹ lara ọkunrin na, ki on ki o jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje; ati gbogbo akete ti on dubulẹ lé ki o jẹ́ aimọ́.

25. Ati bi obinrin kan ba ní isun ẹ̀jẹ li ọjọ́ pupọ̀ le ìgba ìyasapakan rẹ̀; tabi bi o ba si sun rekọja ìgba ìyasapakan rẹ̀; gbogbo ọjọ́ isun aimọ́ rẹ̀ yio si ri bi ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀: o jẹ́ alaimọ́.

26. Gbogbo akete ti o dubulẹ lé ni gbogbo ọjọ́ isun rẹ̀ ki o si jẹ́ fun u bi akete ìyasapakan rẹ̀: ati ohunkohun ti o joko lé ki o jẹ́ aimọ́, bi aimọ́ ìyasapakan rẹ̀.

27. Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn nkan wọnni ki o jẹ́ alaimọ́, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ̀ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

28. Ṣugbọn bi obinrin na ba di mimọ́ kuro ninu isun rẹ̀, nigbana ni ki o kà ijọ́ meje fun ara rẹ̀, lẹhin eyinì ni ki o si jẹ́ mimọ́.

29. Ati ni ijọ́ kẹjọ ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji fun ara rẹ̀, ki o si mú wọn tọ̀ alufa wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.

30. Ki alufa ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun; ki alufa ki o si ṣètutu fun u niwaju OLUWA nitori isun aimọ́ rẹ̀.

31. Bayi ni ki ẹnyin ki o yà awọn ọmọ Israeli kuro ninu aimọ́ wọn; ki nwọn ki o má ba kú ninu aimọ́ wọn, nigbati nwọn ba sọ ibugbé mi ti mbẹ lãrin wọn di aimọ́.

32. Eyi li ofin ẹniti o ní isun, ati ti ẹniti ohun irú rẹ̀ jade lara rẹ̀, ti o si ti ipa rẹ̀ di alaimọ́;

33. Ati ti ẹniti o ri ohun obinrin rẹ̀, ati ti ẹniti o ní isun, ati ti ọkunrin, ati ti obinrin, ati ti ẹniti o ba bá ẹniti iṣe alaimọ́ dàpọ.