9. Bi o ba si ṣepe ẹran ni, ninu eyiti enia mú ọrẹ-ẹbọ tọ̀ OLUWA wá, gbogbo eyiti ẹnikẹni ba múwa ninu irú nkan wọnni fun OLUWA ki o jẹ́ mimọ́.
10. On kò gbọdọ pa a dà, bẹ̃ni kò gbọdọ pàrọ rẹ̀, rere fun buburu, tabi buburu fun rere: bi o ba ṣepe yio pàrọ rẹ̀ rára, ẹran fun ẹran, njẹ on ati ipàrọ rẹ̀ yio si jẹ́ mimọ́.
11. Bi o ba si ṣepe ẹran alaimọ́ kan ni, ninu eyiti nwọn kò mú rubọ si OLUWA, njẹ ki o mú ẹran na wá siwaju alufa:
12. Ki alufa ki o si diyelé e, ibaṣe rere tabi buburu: bi iwọ alufa ba ti diyelé e, bẹ̃ni ki o ri.
13. Ṣugbọn bi o ba fẹ́ rà a pada rára, njẹ ki o fi idamarun rẹ̀ kún idiyelé rẹ.
14. Bi enia kan yio ba si yà ile rẹ̀ sọtọ̀ lati jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, njẹ ki alufa ki o diyelé e, ibaṣe rere tabi buburu: bi alufa ba ti diyelé e, bẹ̃ni ki o ri.
15. Ati bi ẹniti o yà a sọ̀tọ ba nfẹ́ rà ile rẹ̀ pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ̀ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀.
16. Bi enia kan ba si nfẹ́ yà ninu oko ti o jogún sọ̀tọ fun OLUWA, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ bi irugbìn rẹ̀: òṣuwọn homeri irugbìn barle kan ãdọta ṣekeli fadakà.
17. Bi o ba yà oko rẹ̀ sọ̀tọ lati ọdún jubeli wá, gẹgẹ bi idiyelé rẹ bẹ̃ni ki o ri.
18. Ṣugbọn bi o ba yà oko rẹ̀ sọtọ̀ lẹhin ọdún jubeli, njẹ ki alufa ki o ṣìro owo rẹ̀ fun u, gẹgẹ bi ìwọn ọdún ti o kù, titi di ọdún jubeli, a o si din i kù ninu idiyelé rẹ.
19. Ati bi ẹniti o yà oko na sọtọ̀ ba fẹ́ rà a pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀.