14. Bi enia kan yio ba si yà ile rẹ̀ sọtọ̀ lati jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, njẹ ki alufa ki o diyelé e, ibaṣe rere tabi buburu: bi alufa ba ti diyelé e, bẹ̃ni ki o ri.
15. Ati bi ẹniti o yà a sọ̀tọ ba nfẹ́ rà ile rẹ̀ pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ̀ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀.
16. Bi enia kan ba si nfẹ́ yà ninu oko ti o jogún sọ̀tọ fun OLUWA, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ bi irugbìn rẹ̀: òṣuwọn homeri irugbìn barle kan ãdọta ṣekeli fadakà.
17. Bi o ba yà oko rẹ̀ sọ̀tọ lati ọdún jubeli wá, gẹgẹ bi idiyelé rẹ bẹ̃ni ki o ri.
18. Ṣugbọn bi o ba yà oko rẹ̀ sọtọ̀ lẹhin ọdún jubeli, njẹ ki alufa ki o ṣìro owo rẹ̀ fun u, gẹgẹ bi ìwọn ọdún ti o kù, titi di ọdún jubeli, a o si din i kù ninu idiyelé rẹ.
19. Ati bi ẹniti o yà oko na sọtọ̀ ba fẹ́ rà a pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀.
20. Bi on kò ba si fẹ́ rà oko na pada, tabi bi o ba ti tà oko na fun ẹlomiran, ki a máṣe rà a pada mọ́.
21. Ṣugbọn oko na, nigbati o ba yọ li ọdún jubeli, ki o jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, bi oko ìya-sọtọ; iní rẹ̀ yio jẹ́ ti alufa.
22. Ati bi ẹnikan ba yà oko kan sọ̀tọ fun OLUWA ti on ti rà, ti ki iṣe ninu oko ti o jogún;
23. Njẹ ki alufa ki o ṣìro iye idiyelé rẹ̀ fun u, titi di ọdún jubeli: ki on ki o si fi idiyelé rẹ li ọjọ́ na, bi ohun mimọ́ fun OLUWA.
24. Li ọdún jubeli ni ki oko na ki o pada sọdọ ẹniti o rà a, ani sọdọ rẹ̀ ti ẹniti ini ilẹ na iṣe.