Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 26:32-42 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Emi o si sọ ilẹ na di ahoro: ẹnu yio si yà awọn ọtá nyin ti ngbé inu rẹ̀ si i.

33. Emi o si tú nyin ká sinu awọn orilẹ-ède, emi o si yọ idà tì nyin lẹhin: ilẹ nyin yio si di ahoro, ati ilu nyin yio di ahoro.

34. Nigbana ni ilẹ na yio ní isimi rẹ̀, ni gbogbo ọjọ́ idahoro rẹ̀, ẹnyin o si wà ni ilẹ awọn ọtá nyin; nigbana ni ilẹ yio simi, ti yio si ní isimi rẹ̀.

35. Ni gbogbo ọjọ́ idahoro rẹ̀ ni yio ma simi; nitoripe on kò simi li ọjọ́-isimi nyin, nigbati ẹnyin ngbé inu rẹ̀.

36. Ati lara awọn ti o kù lãye ninu nyin, li emi o rán ijàiya si ọkàn wọn ni ilẹ awọn ọtá wọn: iró mimì ewé yio si ma lé wọn; nwọn o si sá, bi ẹni sá fun idà; nwọn o si ma ṣubu nigbati ẹnikan kò lepa.

37. Nwọn o si ma ṣubulù ara wọn, bi ẹnipe niwaju idà, nigbati kò sí ẹniti nlepa: ẹnyin ki yio si lí agbara lati duro niwaju awọn ọtá nyin.

38. Ẹnyin o si ṣegbé ninu awọn orilẹ-ède, ilẹ awọn ọtá nyin yio si mú nyin jẹ.

39. Ati awọn ti o kù ninu nyin yio si joro ninu ẹ̀ṣẹ wọn ni ilẹ awọn ọtá nyin; ati nitori ẹ̀ṣẹ awọn baba wọn pẹlu ni nwọn o ma joro pẹlu wọn.

40. Bi nwọn ba si jẹwọ irekọja wọn, ati irekọja awọn baba wọn, pẹlu ọ̀tẹ wọn ti nwọn ti ṣe si mi, ati pẹlu nitoripe nwọn ti rìn lodi si mi;

41. Emi pẹlu rìn lodi si wọn, mo si mú wọn wá si ilẹ awọn ọtá wọn: njẹ bi àiya wọn alaikọlà ba rẹ̀silẹ, ti nwọn ba si gbà ibawi ẹ̀ṣẹ wọn;

42. Nigbana li emi o ranti majẹmu mi pẹlu Jakobu; ati majẹmu mi pẹlu Isaaki, ati majẹmu mi pẹlu Abrahamu li emi o ranti; emi o si ranti ilẹ na.

Ka pipe ipin Lef 26