Ati lara awọn ti o kù lãye ninu nyin, li emi o rán ijàiya si ọkàn wọn ni ilẹ awọn ọtá wọn: iró mimì ewé yio si ma lé wọn; nwọn o si sá, bi ẹni sá fun idà; nwọn o si ma ṣubu nigbati ẹnikan kò lepa.