Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 26:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẸNYIN kò gbọdọ yá oriṣa, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ gbé ere tabi ọwọ̀n kan dide naró fun ara nyin, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ gbé ere okuta gbigbẹ kalẹ ni ilẹ nyin, lati tẹriba fun u: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

2. Ki ẹnyin ki o pa ọjọ́-isimi mi mọ́, ki ẹ si bọ̀wọ fun ibi mimọ́ mi: Emi li OLUWA.

3. Bi ẹnyin ba nrìn ninu ìlana mi, ti ẹ si npa ofin mi mọ́, ti ẹ si nṣe wọn;

4. Nigbana li emi o fun nyin li òjo li akokò rẹ̀, ilẹ yio si ma mú ibisi rẹ̀ wá, igi oko yio si ma so eso wọn.

5. Ipakà nyin yio si dé ìgba ikore àjara, igba ikore àjara yio si dé ìgba ifunrugbìn: ẹnyin o si ma jẹ onjẹ nyin li ajẹyo, ẹ o si ma gbé ilẹ nyin li ailewu.

6. Emi o si fi alafia si ilẹ na, ẹnyin o si dubulẹ, kò si sí ẹniti yio dẹruba nyin: emi o si mu ki ẹranko buburu ki o dasẹ kuro ni ilẹ na, bẹ̃ni idà ki yio là ilẹ nyin já.

7. Ẹnyin o si lé awọn ọtá nyin, nwọn o si ti ipa idà ṣubu niwaju nyin.

8. Marun ninu nyin yio si lé ọgọrun, ọgọrun ninu nyin yio si lé ẹgbarun: awọn ọtá nyin yio si ti ipa idà ṣubu niwaju nyin.

9. Nitoriti emi o fi ojurere wò nyin, emi o si mu nyin bisi i, emi o si sọ nyin di pupọ̀, emi o si gbé majẹmu mi kalẹ pẹlu nyin.

10. Ẹnyin o si ma jẹ ohun isigbẹ, ẹnyin o si ma kó ohun ẹgbẹ jade nitori ohun titun.

11. Emi o si gbé ibugbé mi kalẹ lãrin nyin: ọkàn mi ki yio si korira nyin.

12. Emi o si ma rìn lãrin nyin, emi o si ma ṣe Ọlọrun nyin, ẹnyin o si ma ṣe enia mi.

Ka pipe ipin Lef 26