Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 25:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose li òke Sinai pe,

2. Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ ti mo fi fun nyin, nigbana ni ki ilẹ na ki o pa isimi kan mọ́ fun OLUWA.

3. Ọdún mẹfa ni iwọ o fi gbìn oko rẹ, ọdún mẹfa ni iwọ o si fi rẹwọ ọgbà-ajara rẹ, ti iwọ o si kó eso rẹ̀ jọ;

4. Ṣugbọn ọdún keje ki o si jasi ìgba isimi fun ilẹ na, isimi fun OLUWA: iwọ kò gbọdọ gbìn oko rẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ rẹwọ ọgbà-àjara rẹ.

5. Eyiti o ba lalẹ̀ hù ninu ikore rẹ iwọ kò gbọdọ ká, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ká eso àjara rẹ ti iwọ kò rẹ́ lọwọ: nitoripe ọdún isimi ni fun ilẹ na.

6. Ọdún isimi ilẹ na yio si ma ṣe ohunjijẹ fun nyin; fun iwọ, ati fun iranṣẹ rẹ ọkunrin, ati fun iranṣẹ rẹ obinrin, ati fun alagbaṣe rẹ, ati fun alejò rẹ ti nṣe atipo lọdọ rẹ;

7. Ati fun ohunọ̀sin rẹ, ati fun ẹran ti mbẹ ni ilẹ rẹ, ni ki ibisi rẹ̀ gbogbo ki o ṣe onjẹ fun.

8. Ki iwọ ki o si kà ọdún isimi meje fun ara rẹ, ọdún meje ìgba meje; ati akokò ọdún isimi meje ni yio jẹ́ ọdún mọkandilãdọta fun ọ.

9. Ki iwọ ki o si mu ki ipè ki o dún ni ijọ́ kẹwa oṣù keje, li ọjọ́ ètutu ni ki ẹnyin ki o mu ipè na dún ni gbogbo ilẹ nyin.

10. Ki ẹnyin ki o si yà arãdọta ọdún simimọ́, ki ẹnyin ki o si kede idasilẹ ni ilẹ na fun gbogbo awọn ti ngbé inu rẹ̀: yio si ma jẹ́ jubeli fun nyin; ki ẹnyin ki o si pada olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀, ki olukuluku nyin ki o si pada sinu idile rẹ̀.

11. Ọdún jubeli ni ki arãdọta ọdún ki o jasi fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ gbìn, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ká ilalẹ-hù inu rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ká eso àjara rẹ̀ ti a kò rẹ-lọwọ.

12. Nitoripe jubeli ni; mimọ́ ni ki o jasi fun nyin: ibisi rẹ̀ ni ki ẹnyin o ma jẹ lati inu oko wa.

Ka pipe ipin Lef 25