Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 22:19-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Ki o le dà fun nyin, akọ alailabùkun ni ki ẹnyin ki o fi ru u, ninu malu, tabi ninu agutan, tabi ninu ewurẹ.

20. Ṣugbọn ohunkohun ti o ní abùku, li ẹnyin kò gbọdọ múwa: nitoripe ki yio dà fun nyin.

21. Ati ẹnikẹni ti o ba ru ẹbọ alafia si OLUWA, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwá ni malu tabi agutan, ki o pé ki o ba le dà; ki o máṣe sí abùku kan ninu rẹ̀.

22. Afọju, tabi fifàya, tabi eyiti a palara, tabi elegbo, elekuru, tabi oni-ipẹ́, wọnyi li ẹnyin kò gbọdọ fi rubọ si OLUWA, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ fi ninu wọn ṣe ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA lori pẹpẹ.

23. Ibaṣe akọmalu tabi ọdọ-agutan ti o ní ohun ileke kan, tabi ohun abùku kan, eyinì ni ki iwọ ma fi ru ẹbọ ifẹ́-atinuwá; ṣugbọn fun ẹjẹ́ ki yio dà.

24. Ẹnyin kò gbọdọ mú eyiti kóro rẹ̀ fọ́, tabi ti a tẹ̀, tabi ti a ya, tabi ti a là, wá rubọ si OLUWA; ki ẹnyin máṣe e ni ilẹ nyin.

25. Bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ ti ọwọ́ alejò rubọ àkara Ọlọrun nyin ninu gbogbo wọnyi; nitoripe ibàjẹ́ wọn mbẹ ninu wọn, abùku si mbẹ ninu wọn: nwọn ki yio dà fun nyin.

26. OLUWA si sọ fun Mose pe,

27. Nigbati a ba bi akọmalu kan, tabi agutan kan, tabi ewurẹ kan, nigbana ni ki o gbé ijọ meje lọdọ iya rẹ̀; ati lati ijọ́ kẹjọ ati titi lọ on o di itẹwọgbà fun ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.

28. Ibaṣe abomalu tabi agutan, ẹnyin kò gbọdọ pa a ati ọmọ rẹ̀ li ọjọ́ kanna.

Ka pipe ipin Lef 22