Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 21:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, ki o si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu awọn enia rẹ̀ kò gbọdọ di alaimọ́ nitori okú.

2. Bikoṣe fun ibatan rẹ̀ ti o sunmọ ọ, eyinì ni, iya rẹ̀, ati baba rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọ rẹ̀ obinrin, ati arakunrin rẹ̀;

3. Ati arabinrin rẹ̀ ti iṣe wundia, ti o wà lọdọ rẹ̀, ti kò ti ilí ọkọ, nitori rẹ̀ ni ki o di alaimọ́.

4. Ṣugbọn on kò gbọdọ ṣe ara rẹ̀ li aimọ́, lati bà ara rẹ̀ jẹ́, olori kan sa ni ninu awọn enia rẹ̀.

5. Nwọn kò gbọdọ dá ori wọn fá, bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ tọ́ irungbọn wọn, tabi singbẹrẹ kan si ara wọn.

6. Ki nwọn ki o si jasi mimọ́ fun Ọlọrun wọn, ki nwọn ki o má si ṣe bà orukọ Ọlọrun wọn jẹ́: nitoripe ẹbọ OLUWA ti a fi ina ṣe, ati àkara Ọlọrun wọn, ni nwọn fi nrubọ: nitorina ni ki nwọn ki o jẹ́ mimọ́.

7. Nwọn kò gbọdọ fẹ́ aya ti iṣe àgbere, tabi ẹni ibàjẹ́; bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ fẹ́ obinrin ti a ti ọdọ ọkọ rẹ̀ kọ̀silẹ: nitoripe mimọ́ li on fun Ọlọrun rẹ̀.

8. Nitorina ki ẹnyin ki o yà a simimọ́; nitoriti o nrubọ àkara Ọlọrun rẹ: yio jẹ́ mimọ́ si ọ: nitoripe mimọ́ li Emi OLUWA, ti o yà nyin simimọ́.

9. Ati bi ọmọbinrin alufa kan, ba fi iṣẹ àgbere bà ara rẹ̀ jẹ́, o bà baba rẹ̀ jẹ́: iná li a o da sun u.

10. Ati olori alufa ninu awọn arakunrin rẹ̀, ori ẹniti a dà oróro itasori si, ti a si yàsọtọ lati ma wọ̀ aṣọ wọnni, ki o máṣe ṣi ibori rẹ̀, tabi ki o fà aṣọ rẹ̀ ya;

11. Ki o má si ṣe wọle tọ̀ okú kan lọ, bẹ̃ni ki o máṣe sọ ara rẹ̀ di alaimọ́ nitori baba rẹ̀, tabi nitori iya rẹ̀;

Ka pipe ipin Lef 21