Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 14:32-44 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Eyi li ofin rẹ̀ li ara ẹniti àrun ẹ̀tẹ wà, apa ẹniti kò le ka ohun ìwẹnumọ́ rẹ̀.

33. OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,

34. Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ Kenaani, ti mo fi fun nyin ni ilẹ-iní, ti mo ba si fi àrun ẹ̀tẹ sinu ile kan ninu ilẹ-iní nyin;

35. Ti onile na si wá ti o si wi fun alufa pe, O jọ li oju mi bi ẹnipe àrun mbẹ ninu ile na:

36. Nigbana ni ki alufa ki o fun wọn li aṣẹ, ki nwọn ki o kó ohun ile na jade, ki alufa ki o to wọ̀ inu rẹ̀ lọ lati wò àrun na, ki ohun gbogbo ti mbẹ ninu ile na ki o máṣe jẹ́ alaimọ́: lẹhin eyinì ni ki alufa ki o wọ̀ ọ lati wò ile na:

37. Ki o si wò àrun na, si kiyesi i, bi àrun na ba mbẹ lara ogiri ile na pẹlu ìla gbòrogbòro, bi ẹni ṣe bi ọbẹdò tabi pupa rusurusu, ti o jìn li oju jù ogiri lọ;

38. Nigbana ni ki alufa ki o jade ninu ile na si ẹnu-ọ̀na ile na, ki o si há ilẹkun ile na ni ijọ́ meje:

39. Ki alufa ki o tun wá ni ijọ́ keje, ki o si wò o: si kiyesi i, bi àrun na ba ràn lara ogiri ile na;

40. Nigbana ni ki alufa ki o paṣẹ ki nwọn ki o yọ okuta na kuro lara eyiti àrun na gbé wà, ki nwọn ki o si kó wọn lọ si ibi aimọ́ kan lẹhin ilu na:

41. Ki o si mu ki nwọn ki o ha inu ile na yiká kiri, ki nwọn ki o kó erupẹ ti a ha nì kuro lọ si ẹhin ilu na si ibi aimọ́ kan:

42. Ki nwọn ki o si mú okuta miran, ki nwọn ki o si fi i di ipò okuta wọnni, ki nwọn ki o si mú ọrọ miran ki nwọn ki o si fi rẹ́ ile na.

43. Bi àrùn na ba si tun pada wá, ti o si tun sọ jade ninu ile na, lẹhin igbati nwọn ba yọ okuta wọnni kuro, ati lẹhin igbati nwọn ba ha ile na, ati lẹhin igbati nwọn ba rẹ́ ẹ;

44. Nigbana ni ki alufa ki o wá, ki o wò o, si kiyesi i, bi àrun ba ràn si i ninu ile na, ẹ̀tẹ kikẹ̀ ni mbẹ ninu ile na: aimọ́ ni.

Ka pipe ipin Lef 14