Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 13:32-47 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Ni ijọ́ keje ki alufa ki o si wò àrun na: si kiyesi i, bi pipa na kò ba ràn, ti kò si sí irun pupa ninu rẹ̀, ti pipa na kò si jìn jù awọ ara lọ li oju,

33. Ki o fári, ṣugbọn ki o máṣe fá ibi pipa na; ki alufa ki o si sé ẹni pipa nì mọ́ ni ijọ́ meje si i:

34. Ni ijọ́ keje ki alufa ki o si wò pipa na; si kiyesi i bi pipa na kò ba ràn si awọ ara, ti kò ba jìn jù awọ ara lọ li oju; nigbana ni ki alufa ki o pè e ni mimọ́: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ mimọ́.

35. Ṣugbọn bi pipa na ba ràn siwaju li awọ ara rẹ̀ lẹhin ìpenimimọ́ rẹ̀;

36. Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi pipa na ba ràn siwaju li awọ ara, ki alufa ki o máṣe wá irun pupa mọ́; alaimọ́ ni.

37. Ṣugbọn li oju rẹ̀ bi pipa na ba duro, ti irun dudu si hù ninu rẹ̀; pipa na jiná, mimọ́ li on: ki alufa ki o pè e ni mimọ́.

38. Bi ọkunrin kan tabi obinrin kan ba ní àmi didán li awọ ara wọn, ani àmi funfun didán;

39. Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi àmi didán li awọ ara wọn ba ṣe bi ẹni ṣe funfun ṣe dudu; ifinra li o sọ jade li ara; mimọ́ li on.

40. Ati ọkunrin ti irun rẹ̀ ba re kuro li ori rẹ̀, apari ni; ṣugbọn mimọ́ li on.

41. Ẹniti irun rẹ̀ ba re silẹ ni ìha iwaju rẹ̀, o pari ni iwaju; ṣugbọn mimọ́ li on.

42. Bi õju funfun-pupa rusurusu ba mbẹ li ori pipa na, tabi iwaju ori pipa na; ẹ̀tẹ li o sọ jade ninu pipa ori na, tabi ni pipá iwaju na.

43. Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi iwú õju na ba funfun-pupa rusurusu ni pipa ori rẹ̀, tabi pipa iwaju rẹ̀, bi ẹ̀tẹ ti ihàn li awọ ara;

44. Ẹlẹtẹ ni, alaimọ́ ni: ki alufa ki o pè e li aimọ́ patapata; àrun rẹ̀ mbẹ li ori rẹ̀.

45. Ati adẹ́tẹ na, li ara ẹniti àrun na gbé wà, ki o fà aṣọ rẹ̀ ya, ki o si fi ori rẹ̀ silẹ ni ìhoho, ki o si fi ìbo bò ète rẹ̀ òke, ki o si ma kepe, Alaimọ́, alaimọ́.

46. Ni gbogbo ọjọ́ ti àrun na mbẹ li ara rẹ̀ ni ki o jẹ́ elẽri; alaimọ́ ni: on nikan ni ki o ma gbé; lẹhin ibudó ni ibujoko rẹ̀ yio gbé wà.

47. Ati aṣọ ti àrun ẹ̀tẹ mbẹ ninu rẹ̀, iba ṣe aṣọ kubusu, tabi aṣọ ọ̀gbọ;

Ka pipe ipin Lef 13