Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 10:12-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Mose si wi fun Aaroni, ati fun Eleasari ati fun Itamari, awọn ọmọ rẹ̀ ti o kù pe, Ẹ mú ẹbọ ohunjijẹ ti o kù ninu ẹbọ OLUWA, ti a fi iná ṣe, ki ẹ si jẹ ẹ lainí iwukàra lẹba pẹpẹ: nitoripe mimọ́ julọ ni:

13. Ki ẹnyin ki o si jẹ ẹ ni ibi mimọ́, nitoripe ipín tirẹ, ati ipín awọn ọmọ rẹ ni, ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: nitoripe, bẹ̃li a fi aṣẹ fun mi.

14. Ati igẹ̀ fifì, ati itan agbesọsoke ni ki ẹnyin ki o jẹ ni ibi mimọ́ kan; iwọ, ati awọn ọmọkunrin rẹ, ati awọn ọmọbinrin rẹ pẹlu rẹ: nitoripe ipín tirẹ ni, ati ipín awọn ọmọ rẹ, ti a fi fun nyin ninu ẹbọ alafia awọn ọmọ Israeli.

15. Itan agbesọsoke ati igẹ̀ fifì ni ki nwọn ki o ma múwa pẹlu ẹbọ ti a fi iná ṣe ti ọrá, lati fì i fun ẹbọ fifì niwaju OLUWA: yio si ma jẹ́ tirẹ, ati ti awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ, nipa ìlana titilai; bi OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ.

16. Mose si fi pẹlẹpẹlẹ wá ewurẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì, si kiyesi i, a ti sun u: o si binu si Eleasari ati Itamari, awọn ọmọ Aaroni ti o kù, wipe,

17. Nitori kini ẹnyin kò ṣe jẹ ẹbọ èṣẹ na ni ibi mimọ́, nitoripe mimọ́ julọ ni, a si ti fi fun nyin lati rù ẹ̀ṣẹ ijọ enia, lati ṣètutu fun wọn niwaju OLUWA?

18. Kiyesi i, a kò mú ẹ̀jẹ rẹ̀ wá sinu ibi mimọ́: ẹnyin iba ti jẹ ẹ nitõtọ ni ibi mimọ́, bi mo ti paṣẹ.

19. Aaroni si wi fun Mose pe, Kiyesi i, li oni ni nwọn ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn ati ẹbọ sisun wọn niwaju OLUWA; irú nkan wọnyi li o si ṣubulù mi: emi iba si ti jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ li oni, o ha le dara li oju OLUWA?

20. Nigbati Mose gbọ́ eyi inu rẹ̀ si tutù.

Ka pipe ipin Lef 10