orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 36 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ELIHU si sọ si i lọ wipe,

2. Bùn mi laye diẹ, emi o si fi hàn ọ, nitori ọ̀rọ sisọ ni o kù fun Ọlọrun.

3. Emi o mu ìmọ mi ti ọ̀na jijin wá, emi o si fi ododo fun Ẹlẹda mi.

4. Nitoripe ọ̀rọ mi kì yio ṣeke nitõtọ, ẹniti o pé ni ìmọ wà pẹlu rẹ.

5. Kiyesi i, Ọlọrun li agbara, kò si gàn ẹnikẹni, o li agbara ni ipá ati oye.

6. On kì ida ẹmi enia buburu sí, ṣugbọn o fi otitọ fun awọn talaka.

7. On kì imu oju rẹ̀ kuro lara olododo, ṣugbọn pẹlu awọn ọba ni nwọn wà lori itẹ; ani o fi idi wọn mulẹ lailai, a si gbe wọn lekè.

8. Bi a ba si dè wọn ninu àba, ti a si fi okun ipọnju dè wọn,

9. Nigbana ni ifi iṣẹ wọn hàn fun wọn, ati irekọja wọn ti nwọn fi gbe ara wọn ga.

10. O ṣi wọn leti pẹlu si ọ̀na ẹkọ́, o si paṣẹ ki nwọn ki o pada kuro ninu aiṣedede.

11. Bi nwọn ba gbagbọ, ti nwọn si sin i, nwọn o lò ọjọ wọn ninu ìrọra, ati ọdun wọn ninu afẹ́.

12. Ṣugbọn bi nwọn kò ba gbagbọ, nwọn o ti ọwọ idà ṣègbe, nwọn a si kú laini oye.

13. Ṣugbọn awọn àgabagebe li aiya kó ibinu jọ; nwọn kò kigbe nigbati o ba dè wọn.

14. Nigbana ni ọkàn wọn yio kú li ewe, ẹmi wọn a si wà ninu awọn oniwa Sodomu.

15. On gba otoṣi ninu ipọnju rẹ̀, a si ṣi wọn li eti ninu inilara.

16. Bẹ̃ni pẹlupẹlu o si dẹ̀ ọ lọ lati inu ihagaga si ibi gbõrò, ti kò ni wahala ninu rẹ̀; ati ohun ti a si gbe kalẹ ni tabeli rẹ, a jẹ kiki ọ̀ra.

17. Ṣugbọn iwọ kún fun idajọ awọn enia buburu; idajọ ati otitọ di ọ mu.

18. Nitori ibinu mbẹ, ṣọra ki titó rẹ ma bà tàn ọ lọ; má si ṣe jẹ ki titobi irapada mu ọ ṣìna.

19. Ọrọ̀ rẹ pọ̀ to, ti wahala kì yio fi de ba ọ bi? tabi ipá agbara rẹ?

20. Má ṣe ifẹ oru, nigbati a nke awọn orilẹ-ède kuro ni ipo wọn.

21. Ma ṣọra ki iwọ ki o má yi ara rẹ pada si asan, nitori eyi ni iwọ ti ṣàyan jù sũru lọ.

22. Kiyesi i, Ọlọrun a gbeni ga nipa agbara rẹ̀, tani jẹ olukọni bi on?

23. Tali o là ọ̀na-iṣẹ rẹ̀ silẹ fun u, tabi tali o lè wipe, Iwọ ti nṣe aiṣedede?

24. Ranti ki iwọ ki o gbe iṣẹ́ rẹ̀ ga, ti enia ima kọrin si.

25. Olukuluku enia a ma ri i, ẹni-ikú a ma wò o li okere.

26. Kiyesi i, Ọlọrun tobi, awa kò si mọ̀ bi o ti tobi to! bẹ̃ni a kò le wadi iye ọdun rẹ̀ ri.

27. Nitoripe on li o fa ikán omi ojo silẹ, ki nwọn ki o kán bi ojo ni ikuku rẹ̀.

28. Ti awọsanma nrọ̀, ti o si nfi sẹ̀ lọpọlọpọ lori enia.

29. Pẹlupẹlu ẹnikẹni le imọ̀ itanká awọsanma, tabi ariwo agọ rẹ̀?

30. Kiyesi i, o tàn imọlẹ yi ara rẹ̀ ka, o si fi isalẹ omi okun bò ara rẹ̀ mọlẹ.

31. Nitoripe nipa wọn ni nṣe idajọ enia, o fun ni li onjẹ li ọ̀pọlọpọ.

32. O fi imọlẹ̀ bò ọwọ rẹ̀ mejeji, o si ran a si ẹni olodi.

33. Ariwo ãrá rẹ̀ fi i han ni, ọ̀wọ-ẹran pẹlu wipe, O sunmọ etile!