orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 35 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ELIHU sọ pẹlu o si wipe,

2. Iwọ rò pe eyi ha tọ́, ti iwọ wipe, ododo mi ni eyi niwaju Ọlọrun pe,

3. Nitoriti iwọ wipe, Ère kini yio jasi fun ọ, tabi ère kili emi o fi jẹ jù ère ẹ̀ṣẹ mi lọ?

4. Emi o da ọ lohùn ati awọn ẹgbẹ rẹ pẹlu rẹ.

5. Ṣiju wò ọrun, ki o ri i, ki o si bojuwo awọsanma ti o ga jù ọ lọ.

6. Bi iwọ ba ṣẹ̀ kini iwọ fi ṣe si i? tabi bi irekọja rẹ di pupọ, kini iwọ fi eyini ṣe si i?

7. Bi iwọ ba si ṣe olododo, kini iwọ fi bùn u, tabi kili on ri gbà lati ọwọ rẹ wá?

8. Ìwa buburu rẹ ni fun enia bi iwọ; ododo rẹ si ni fun ọmọ enia.

9. Nipa ọ̀pọlọpọ ininilara nwọn mu ni kigbe, nwọn kigbe nitori apá awọn alagbara.

10. Ṣugbọn kò si ẹniti o wipe, Nibo ni Ọlọrun Ẹlẹda mi wà, ti o fi orin fun mi li oru?

11. Ti on kọ́ wa li ẹkọ́ jù awọn ẹranko aiye lọ, ti o si mu wa gbọ́n jù awọn ẹiyẹ oju ọrun lọ.

12. Nigbana ni nwọn ke, ṣugbọn Ọlọrun kò dahùn nitori igberaga awọn enia buburu.

13. Nitõtọ Ọlọrun kì yio gbọ́ asan, bẹ̃ni Olodumare kì yio kà a si.

14. Bi o tilẹ ṣepe iwọ wipe, iwọ kì iri i, ọran idajọ mbẹ niwaju rẹ̀, ẹniti iwọ si gbẹkẹle.

15. Ṣugbọn nisisiyi nitoriti ibinu rẹ̀ kò ti ṣẹ́ ọ niṣẹ, on kò ha le imọ̀ ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ bi?

16. Nitorina ni Jobu ṣe ya ẹnu rẹ̀ lasan, o sọ ọ̀rọ di pupọ laisi ìmọ.