orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 17 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EMI mi bajẹ, ọjọ mi parun, isa-okú duro dè mi.

2. Nitõtọ! awọn ẹlẹya wà lọdọ mi, oju mi si tẹmọ́ imunibinu wọn.

3. Njẹ nisisiyi, fi lelẹ! yàn onigbọwọ fun mi lọdọ rẹ; tani oluwa rẹ̀ ti yio ba mi so ọwọ pọ̀?

4. Nitoripe iwọ ti sé wọn laiya kuro ninu oye, nitorina iwọ kì yio gbé wọn leke.

5. Ẹniti o fi awọn ọrẹ hàn fun igára, on ni oju awọn ọmọ rẹ̀ yio mu ofo.

6. O si sọ mi di ẹni-owe fun awọn enia, niwaju wọn ni mo dabi ẹni itutọ́ si li oju.

7. Oju mi ṣú baibai pẹlu nitori ibinujẹ, gbogbo ẹ̀ya ara mi si dabi ojiji.

8. Awọn olododo yio yanu si eyi, ẹni alaiṣẹ̀ si binu si awọn àgabagebe.

9. Olododo pẹlu yio di ọ̀na rẹ̀ mu, ati ọlọwọ mimọ́ yio ma lera siwaju.

10. Ṣugbọn bi o ṣe ti gbogbo nyin, ẹ yipada, ki ẹ si tun bọ̀ nisisiyi, emi kò le ri ọlọgbón kan ninu nyin.

11. Ọjọ ti emi ti kọja, iro mi ti fà já, ani iro inu mi.

12. A sọ oru di ọ̀san; nwọn ni, imọlẹ sunmọ ibiti òkunkun de.

13. Bi mo tilẹ ni ireti, ipo-okú ni ile mi, mo ti tẹ bùsun mi sinu òkunkun.

14. Emi ti wi fun idibajẹ pe, Iwọ ni baba mi, ati fun kòkoro pe, Iwọ ni iya mi ati arabinrin mi.

15. Ireti mi ha dà nisisiyi? bi o ṣe ti ireti mi ni, tani yio ri i?

16. O sọkalẹ lọ sinu ọgbun ipo-okú, nigbati a jumọ simi pọ̀ ninu erupẹ ilẹ.