Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 1:5-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. O si ṣe, nigbati ọjọ àse wọn pé yika, ni Jobu ranṣẹ lọ iyà wọn si mimọ, o si dide ni kùtukutu owurọ, o si rú ẹbọ sisun niwọn iye gbogbo wọn; nitoriti Jobu wipe: bọya awọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, nwọn kò si ṣọpẹ́ fun Ọlọrun lọkàn wọn. Bẹ̃ni Jobu imaṣe nigbagbogbo.

6. Njẹ, o di ọjọ kan, nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wá ipé niwaju Oluwa, Satani si wá pẹlu wọn.

7. Oluwa si bi Satani wipe: nibo ni iwọ ti wá? nigbana ni Satani da Oluwa lohùn wipe: ni ilọ siwá sẹhin lori ilẹ aiye, ati ni irinkerindo ninu rẹ̀.

8. Oluwa si sọ fun Satani pe, Iwọ ha kiyesi Jobu iranṣẹ mi, pe, kò si ekeji rẹ̀ li aiye, ọkunrin ti iṣe olõtọ, ti o si duro ṣinṣin, ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si korira ìwa buburu.

9. Nigbana ni Satani dá Oluwa lohùn wipe: Jobu ha bẹ̀ru Oluwa li asan bi?

10. Iwọ kò ha ti sọgbà yi i ká, ati yi ile rẹ̀ ati yi ohun ti o ni ká ni iha gbogbo? Iwọ busi iṣẹ ọwọ rẹ̀, ohunọ̀sin rẹ̀ si npọsi i ni ilẹ.

Ka pipe ipin Job 1