Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 8:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o má ṣe fò ọ: mú gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ ki iwọ ki o si dide, ki o si gòke lọ si Ai: kiyesi i, emi ti fi ọba Ai, ati awọn enia rẹ̀, ati ilunla rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀ lé ọ lọwọ:

2. Iwọ o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀ gẹgẹ bi iwọ ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀: kìki ikogun rẹ̀, ati ohun-ọ̀sin rẹ̀, li ẹnyin o mú ni ikogun fun ara nyin: rán enia lọ iba lẹhin ilu na.

3. Joṣua si dide, ati gbogbo awọn ọmọ-ogun, lati gòke lọ si Ai: Joṣua si yàn ẹgba mẹdogun, alagbara akọni, o si rán wọn lo li oru.

4. O si paṣẹ fun wọn pe, Wò o, ẹnyin o ba tì ilu na, ani lẹhin ilu na: ẹ má ṣe jìna pupọ̀ si ilu na, ṣugbọn ki gbogbo nyin ki o murasilẹ.

5. Ati emi, ati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu mi, yio sunmọ ilu na: yio si ṣe, nigbati nwọn ba jade si wa, gẹgẹ bi ti ìgba iṣaju, awa o si sá niwaju wọn;

6. Nitoriti nwọn o jade si wa, titi awa o fi fà wọn jade kuro ni ilu; nitoriti nwọn o wipe, Nwọn sá niwaju wa, gẹgẹ bi ti ìgba iṣaju; nitorina li awa o sá niwaju wọn:

7. Nigbana li ẹnyin o dide ni buba, ẹnyin o si gbà ilu na: nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin yio fi i lé nyin lọwọ.

8. Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba gbà ilu na tán, ki ẹnyin ki o si tinabọ ilu na; gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA ni ki ẹnyin ki o ṣe: wò o, mo ti fi aṣẹ fun nyin na.

Ka pipe ipin Joṣ 8