Nitorina ni Joṣua ṣe rán wọn lọ: nwọn lọ iba, nwọn si joko li agbedemeji Beti-eli ati Ai, ni ìha ìwọ-õrùn Ai: ṣugbọn Joṣua dó li oru na lãrin awọn enia.