Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 6:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. (NJẸ a há Jeriko mọ́ gága nitori awọn ọmọ Israeli: ẹnikẹni kò jade, ẹnikẹni kò si wọle.)

2. OLUWA si wi fun Joṣua pe, Wò o, mo ti fi Jeriko lé ọ lọwọ, ati ọba rẹ̀, ati awọn alagbara akọni.

3. Ẹnyin o si ká ilu na mọ́, gbogbo ẹnyin ologun, ẹnyin o si yi ilu na ká lẹ̃kan. Bayi ni iwọ o ṣe ni ijọ́ mẹfa.

4. Alufa meje yio gbé ipè jubeli meje niwaju apoti na: ni ijọ́ keje ẹnyin o si yi ilu na ká lẹ̃meje, awọn alufa yio si fọn ipè wọnni.

5. Yio si ṣe, nigbati nwọn ba fọn ipè jubeli kikan, nigbati ẹnyin ba si gbọ́ iró ipè na, gbogbo awọn enia yio si hó kũ; odi ilu na yio si wó lulẹ, bẹrẹ, awọn enia yio si gòke lọ tàra, olukuluku niwaju rẹ̀.

6. Joṣua ọmọ Nuni si pè awọn alufa, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbé apoti majẹmu na, ki alufa meje ki o gbé ipè jubeli meje nì niwaju apoti OLUWA.

7. O si wi fun awọn enia pe, Ẹ kọja, ki ẹ si yi ilu na ká, ki awọn ti o hamọra ki o si kọja niwaju apoti OLUWA.

Ka pipe ipin Joṣ 6