Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 24:15-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Bi o ba si ṣe buburu li oju nyin lati sìn OLUWA, ẹ yàn ẹniti ẹnyin o ma sìn li oni; bi oriṣa wọnni ni ti awọn baba nyin ti o wà ni ìha keji Odò ti nsìn, tabi awọn oriṣa awọn Amori, ni ilẹ ẹniti ẹnyin ngbé: ṣugbọn bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA li awa o ma sìn.

16. Awọn enia na dahùn, nwọn si wipe, Ki a má ri ti awa o fi kọ̀ OLUWA silẹ, lati sìn oriṣa;

17. Nitori OLUWA Ọlọrun wa, on li ẹniti o mú wa, ati awọn baba wa gòke lati ilẹ Egipti wá, kuro li oko-ẹrú, ti o si ṣe iṣẹ-iyanu nla wọnni li oju wa, ti o si pa wa mọ́ ni gbogbo ọ̀na ti awa rìn, ati lãrin gbogbo enia ti awa là kọja:

18. OLUWA si lé gbogbo awọn enia na jade kuro niwaju wa, ani awọn Amori ti ngbé ilẹ na: nitorina li awa pẹlu o ṣe ma sìn OLUWA; nitori on li Ọlọrun wa.

19. Joṣua si wi fun awọn enia na pe, Enyin kò le sìn OLUWA; nitoripe Ọlọrun mimọ́ li on; Ọlọrun owú li on; ki yio dari irekọja ati ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin.

20. Bi ẹnyin ba kọ̀ OLUWA silẹ, ti ẹ ba si sìn ọlọrun ajeji, nigbana ni on o pada yio si ṣe nyin ni ibi, yio si run nyin, lẹhin ti o ti ṣe nyin li ore tán.

21. Awọn enia na si wi fun Joṣua pe, Rárá o; ṣugbọn OLUWA li awa o sìn.

22. Joṣua si wi fun awọn enia na pe, Ẹnyin li ẹlẹri si ara nyin pe, ẹnyin yàn OLUWA fun ara nyin, lati ma sìn i. Nwọn si wipe, Awa ṣe ẹlẹri.

23. Njẹ nitorina ẹ mu ọlọrun ajeji ti mbẹ lãrin nyin kuro, ki ẹnyin si yi ọkàn nyin si OLUWA Ọlọrun Israeli.

Ka pipe ipin Joṣ 24