Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 21:35-45 Yorùbá Bibeli (YCE)

35. Dimna pẹlu àgbegbe rẹ̀, Nahalali pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin.

36. Ati ninu ẹ̀ya Reubeni, Beseri pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Jahasi pẹlu àgbegbe rẹ̀,

37. Kedemotu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Mefaati pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin.

38. Ati ninu ẹ̀ya Gadi, Ramotu ni Gileadi pẹlu àgbegbe rẹ̀, ilu àbo fun apania; ati Mahanaimu pẹlu àgbegbe rẹ̀.

39. Heṣboni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Jaseri pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin ni gbogbo rẹ̀.

40. Gbogbo wọnyi ni ilu awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi idile wọn, ani awọn ti o kù ni idile awọn ọmọ Lefi; ipín wọn si jẹ́ ilu mejila.

41. Gbogbo ilu awọn ọmọ Lefi ti mbẹ lãrin ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli jẹ́ ilu mejidilãdọta pẹlu àgbegbe wọn.

42. Olukuluku ilu wọnyi li o ní àgbegbe wọn yi wọn ká: bayi ni gbogbo ilu wọnyi ri.

43. OLUWA si fun Israeli ni gbogbo ilẹ na, ti o bura lati fi fun awọn baba wọn; nwọn si gbà a, nwọn si ngbé inu rẹ̀.

44. OLUWA si fun wọn ni isimi yiká kiri, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o bura fun awọn baba wọn: kò si sí ọkunrin kan ninu gbogbo awọn ọtá wọn ti o duro niwaju wọn; OLUWA fi gbogbo awọn ọtá wọn lé wọn lọwọ.

45. Ohunkohun kò tase ninu ohun rere ti OLUWA ti sọ fun ile Israeli; gbogbo rẹ̀ li o ṣẹ.

Ka pipe ipin Joṣ 21