Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 2:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. JOṢUA ọmọ Nuni si rán ọkunrin meji jade lati Ṣittimu yọ lọ ṣe amí, wipe, Ẹ lọ iwò ilẹ na, ati Jeriko. Nwọn si lọ, nwọn si dé ile panṣaga kan, ti a npè ni Rahabu, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.

2. A si sọ fun ọba Jeriko pe, Kiyesi i, awọn ọkunrin kan ninu awọn ọmọ Israeli dé ihinyi li alẹ yi lati rìn ilẹ yi wò.

3. Ọba Jeriko si ranṣẹ si Rahabu, wipe, Mú awọn ọkunrin nì ti o tọ̀ ọ wá, ti o wọ̀ inu ile rẹ jade wá: nitori nwọn wá lati rìn gbogbo ilẹ yi wò.

4. Obinrin na si mú awọn ọkunrin meji na, o si fi wọn pamọ́; o si wi bayi pe, Awọn ọkunrin kan wá sọdọ mi, ṣugbọn emi kò mọ̀ ibi ti nwọn ti wá.

5. O si ṣe li akokò ati tì ilẹkun ẹnubode, nigbati ilẹ ṣú, awọn ọkunrin na si jade lọ: ibi ti awọn ọkunrin na gbé lọ, emi kò mọ̀: ẹ lepa wọn kánkán; nitori ẹnyin o bá wọn.

6. Ṣugbọn o ti mú wọn gòke àja ile, o si fi poroporo ọ̀gbọ ti o ti tòjọ soke àja bò wọn mọlẹ.

7. Awọn ọkunrin na lepa wọn li ọ̀na ti o lọ dé iwọ̀do Jordani: bi awọn ti nlepa wọn si ti jade lọ, nwọn tì ilẹkun ẹnubode.

8. Ki nwọn ki o tó dubulẹ, o gòke tọ̀ wọn lọ loke àja;

9. O si wi fun awọn ọkunrin na pe, Emi mọ̀ pe OLUWA ti fun nyin ni ilẹ yi, ati pe ẹ̀ru nyin bà ni, ati pe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori nyin.

10. Nitoripe awa ti gbọ́ bi OLUWA ti mu omi Okun Pupa gbẹ niwaju nyin, nigbati ẹnyin jade ni Egipti; ati ohun ti ẹnyin ṣe si awọn ọba meji ti awọn Amori, ti mbẹ ni ìha keji Jordani, Sihoni ati Ogu, ti ẹnyin parun tútu.

Ka pipe ipin Joṣ 2