Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 9:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ORI mi iba jẹ omi, ati oju mi iba jẹ orisun omije, ki emi le sọkun lọsan ati loru fun awọn ti a pa ninu ọmọbinrin enia mi!

2. A! emi iba ni buka ero ni iju, ki emi ki o le fi enia mi silẹ, ki nlọ kuro lọdọ wọn! nitori gbogbo nwọn ni panṣaga, ajọ alarekereke enia ni nwọn.

3. Nwọn si fà ahọn wọn bi ọrun fun eke; ṣugbọn nwọn kò ṣe akoso fun otitọ lori ilẹ, nitoripe nwọn ti inu buburu lọ si buburu nwọn kò si mọ̀ mi, li Oluwa wi.

4. Ẹ mã ṣọra, olukuluku nyin lọdọ aladugbo rẹ̀, ki ẹ má si gbẹkẹle arakunrin karakunrin: nitoripe olukuluku arakunrin fi arekereke ṣẹtan patapata, ati olukuluku aladugbo nsọ̀rọ ẹnilẹhin.

5. Ẹnikini ntàn ẹnikeji rẹ̀ jẹ, nwọn kò si sọ otitọ: nwọn ti kọ́ ahọn wọn lati ṣeke, nwọn si ti ṣe ara wọn lãrẹ lati ṣe aiṣedede.

6. Ibugbe rẹ mbẹ lãrin ẹ̀tan; nipa ẹ̀tan nwọn kọ̀ lati mọ̀ mi, li Oluwa wi.

7. Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, sa wò o, emi o yọ́ wọn, emi o si dán wọn wò, nitori kili emi o ṣe fun ọmọbinrin enia mi.

Ka pipe ipin Jer 9