Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 8:9-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Oju tì awọn ọlọgbọ́n, idamu ba wọn a si mu wọn: sa wò o, nwọn ti kọ̀ ọ̀rọ Oluwa! ọgbọ́n wo li o wà ninu wọn?

10. Nitorina ni emi o fi aya wọn fun ẹlomiran, ati oko wọn fun awọn ti yio gbà wọn: nitori gbogbo wọn, lati ẹni kekere titi o fi de enia-nla, fi ara wọn fun ojukokoro, lati woli titi de alufa, gbogbo wọn nṣe ẹ̀tan.

11. Nitoripe nwọn ti wo ipalara ọmọbinrin enia mi fẹrẹ̀ wipe, Alafia! Alafia! nigbati alafia kò si.

12. Itiju yio ba wọn nitori nwọn ti ṣe ohun irira, sibẹ nwọn kò tiju, bẹ̃ni õru itiju kò mu wọn, nitorina ni nwọn o ṣe ṣubu lãrin awọn ti o ṣubu; ni igba ibẹ̀wo wọn, a o si wó wọn lulẹ, li Oluwa wi.

13. Ni kiká emi o ká wọn jọ, li Oluwa wi, eso-àjara kì yio si mọ lori ajara, tabi eso-ọ̀pọtọ lori igi ọ̀pọtọ, ewe rẹ̀ yio si rẹ̀; nitorina ni emi o yàn awọn ti yio kọja lọ lori rẹ̀.

14. Ẽṣe ti awa joko jẹ? ẹ ko ara nyin jọ, ki ẹ si jẹ ki a wọ̀ inu ilu olodi, ki a si dakẹ sibẹ: nitori Oluwa Ọlọrun wa, ti mu wa dakẹ, o si fun wa ni omi orõro lati mu, nitori ti awa ṣẹ̀ si Oluwa.

15. Awa reti alafia, ṣugbọn kò si ireti kan, ati ìgba didá ara, si kiye si i, idamu!

Ka pipe ipin Jer 8