Itiju yio ba wọn nitori nwọn ti ṣe ohun irira, sibẹ nwọn kò tiju, bẹ̃ni õru itiju kò mu wọn, nitorina ni nwọn o ṣe ṣubu lãrin awọn ti o ṣubu; ni igba ibẹ̀wo wọn, a o si wó wọn lulẹ, li Oluwa wi.