Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 8:13-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ni kiká emi o ká wọn jọ, li Oluwa wi, eso-àjara kì yio si mọ lori ajara, tabi eso-ọ̀pọtọ lori igi ọ̀pọtọ, ewe rẹ̀ yio si rẹ̀; nitorina ni emi o yàn awọn ti yio kọja lọ lori rẹ̀.

14. Ẽṣe ti awa joko jẹ? ẹ ko ara nyin jọ, ki ẹ si jẹ ki a wọ̀ inu ilu olodi, ki a si dakẹ sibẹ: nitori Oluwa Ọlọrun wa, ti mu wa dakẹ, o si fun wa ni omi orõro lati mu, nitori ti awa ṣẹ̀ si Oluwa.

15. Awa reti alafia, ṣugbọn kò si ireti kan, ati ìgba didá ara, si kiye si i, idamu!

16. Lati Dani ni a gbọ́ fifọn imu ẹṣin rẹ̀; gbogbo ilẹ warìri fun iro yiyan akọ-ẹṣin rẹ̀; nwọn si de, nwọn si jẹ ile run, ati eyi ti mbẹ ninu rẹ̀: ilu ati awọn ti ngbe inu rẹ̀,

17. Sa wò o, emi o ran ejo, ejo gunte si ãrin nyin, ti kì yio gbọ́ ituju, nwọn o si bu nyin jẹ, li Oluwa wi.

18. Emi iba le tù ara mi ninu, ninu ikãnu mi? ọkàn mi daku ninu mi!

19. Sa wò o, ohùn ẹkún ọmọbinrin enia mi, lati ilẹ jijina wá, Kò ha si Oluwa ni Sioni bi? ọba rẹ̀ kò ha si ninu rẹ̀? ẽṣe ti nwọn fi ere gbigbẹ ati ohun asan àjeji mu mi binu?

20. Ikore ti kọja, ẹ̀run ti pari, a kò si gba wa la!

Ka pipe ipin Jer 8