Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 6:1-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẸNYIN ọmọ Benjamini, ẹ ko ẹrù nyin salọ kuro li arin Jerusalemu, ẹ si fun fère ni Tekoa, ki ẹ si gbe àmi soke ni Bet-hakeremu, nitori ibi farahàn lati ariwa wá; ani iparun nlanla.

2. Emi ti pa ọmọbinrin Sioni run, ti o ṣe ẹlẹgẹ ati ẹlẹwà.

3. Awọn oluṣọ-agutan pẹlu agbo wọn yio tọ̀ ọ wá, nwọn o pa agọ wọn yi i ka olukuluku yio ma jẹ ni àgbegbe rẹ̀.

4. Ẹ ya ara nyin si mimọ́ lati ba a jagun; dide, ki ẹ si jẹ ki a goke li ọsan. Egbe ni fun wa! nitori ọjọ nlọ, nitori ojiji ọjọ alẹ nà jade.

5. Dide, ẹ jẹ ki a goke lọ li oru, ki a si pa ãfin rẹ̀ run.

6. Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ke igi lulẹ, ki ẹ si wà yàra ka Jerusalemu; eyi ni ilu nla ti a o bẹ̀wo; kìki ininilara li o wà lãrin rẹ̀.

7. Bi isun ti itú omi rẹ̀ jade, bẹ̃ni o ntú ìwa-buburu rẹ̀ jade: ìwa-ipa ati ìka li a gbọ́ niwaju mi nigbagbogbo ninu rẹ̀, ani aisan ati ọgbẹ́.

8. Gbọ́ ẹkọ́, Jerusalemu, ki ẹmi mi ki o má ba lọ kuro lọdọ rẹ; ki emi má ba sọ ọ di ahoro, ilẹ ti a kò gbe inu rẹ̀.

9. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, jẹ ki nwọn ki o pẽṣẹ iyokù Israeli bi àjara: yi ọwọ rẹ pada bi aká-eso-ajara sinu agbọ̀n.

10. Tani emi o sọ fun, ti emi o kilọ fun ti nwọn o si gbọ́? sa wò o, eti wọn jẹ alaikọla, nwọn kò si le fi iye si i: sa wò o, ọ̀rọ Oluwa di ẹ̀gan si wọn, nwọn kò ni inu didùn ninu rẹ̀.

11. Nitorina emi kún fun ikannu Oluwa, ãrẹ̀ mu mi lati pa a mọra: tu u jade sori ọmọde ni ita, ati sori ajọ awọn ọmọkunrin pẹlu: nitori a o mu bãle pẹlu aya rẹ̀ ni igbekun, arugbo pẹlu ẹniti o ni ọjọ kikún lori.

12. Ile wọn o di ti ẹlomiran, oko wọn ati aya wọn lakopọ̀: nitori emi o nà ọwọ mi si ori awọn olugbe ilẹ na, li Oluwa wi.

13. Lati kekere wọn titi de nla wọn, gbogbo wọn li o fi ara wọn fun ojukokoro, ati lati woli titi de alufa, gbogbo wọn ni nṣe eke.

14. Nwọn si ti wo ọgbẹ ọmọbinrin enia mi fẹrẹ̀; nwọn wipe, Alafia! Alafia! nigbati kò si alafia.

15. A mu itiju ba wọn, nitoriti nwọn ṣe ohun irira: sibẹ nwọn kò tiju kan pẹlu, pẹlupẹlu õru itiju kò mu wọn: nitorina nwọn o ṣubu lãrin awọn ti o ṣubu: nigbati emi ba bẹ̀ wọn wo, a o wó wọn lulẹ, li Oluwa wi.

16. Bayi li Oluwa wi, ẹ duro li oju ọ̀na, ki ẹ si wò, ki ẹ si bere oju-ọ̀na igbàni, ewo li ọ̀na didara, ki ẹ si rin nibẹ, ẹnyin o si ri isimi fun ọkàn nyin. Ṣugbọn nwọn wipe, Awa kì yio rin.

17. Pẹlupẹlu mo fi oluṣọ sọdọ nyin, ti o wipe, Ẹ fi eti si iro fère. Ṣugbọn nwọn wipe, awa kì yio feti si i.

18. Nitorina, gbọ́, ẹnyin orilẹ-ède, ki ẹ si mọ̀, ẹnyin ijọ enia, ohun ti o wà ninu wọn!

Ka pipe ipin Jer 6