Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 50:20-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Li ọjọ wọnni, ati li akoko na, li Oluwa wi, a o wá aiṣedẽde Israeli kiri, ṣugbọn kì o si mọ́; ati ẹ̀ṣẹ Juda, a kì o si ri wọn: nitori emi o dariji awọn ti mo mu ṣẹkù.

21. Goke lọ si ilẹ ọlọtẹ li ọ̀na meji, ani sori rẹ̀ ati si awọn olugbe ilu Ibẹwo: sọ ọ di ahoro ki o si parun lẹhin wọn, li Oluwa wi, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti emi ti paṣẹ fun ọ.

22. Iró ogun ni ilẹ na, ati ti iparun nla!

23. Bawo li a ti fọ, ti a si ṣẹ olú gbogbo ilẹ aiye! Bawo ni Babeli di ahoro lãrin awọn orilẹ-ède!

24. Emi ti kẹ okùn fun ọ, a si mu ọ, iwọ Babeli, iwọ kò si mọ̀: a ri ọ, a si mu ọ pẹlu, nitoripe iwọ ti ba Oluwa ja.

25. Oluwa ti ṣi ile ohun-ijà rẹ̀ silẹ; o si ti mu ohun-elo ikannu rẹ̀ jade: nitori Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ni iṣẹ́ iṣe ni ilẹ awọn ara Kaldea.

26. Ẹ wá sori rẹ̀ lati opin gbogbo, ṣi ile iṣura rẹ̀ silẹ: ẹ kó o jọ bi òkiti, ki ẹ si yà a sọtọ fun iparun, ẹ máṣe fi iyokù silẹ fun u!

27. Pa gbogbo awọn akọ-malu rẹ̀! nwọn o lọ si ibi pipa: ègbe ni fun wọn! nitori ọjọ wọn de, àkoko ibẹwo wọn.

28. Ohùn awọn ti o salọ, ti o si sala lati ilẹ Babeli wá, lati kede igbẹsan Oluwa Ọlọrun wa ni Sioni, igbẹsan tempili rẹ̀!

29. Pè ọ̀pọlọpọ enia, ani gbogbo tafatafa, sori Babeli, ẹ dótì i yikakiri; má jẹ ki ẹnikan sala: san fun u gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; gẹgẹ bi gbogbo eyi ti o ti ṣe, ẹ ṣe bẹ̃ si i, nitoriti o ti gberaga si Oluwa, si Ẹni-Mimọ Israeli.

30. Nitorina ni awọn ọdọmọdekunrin rẹ̀ yio ṣubu ni ita rẹ̀, ati gbogbo awọn ologun rẹ̀ li a o ke kuro li ọjọ na, li Oluwa wi.

Ka pipe ipin Jer 50