Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 50:2-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ẹ sọ ọ lãrin awọn orilẹ-ède, ẹ si kede, ki ẹ si gbe asia soke: ẹ kede, ẹ má si ṣe bò o: wipe, a kó Babeli, oju tì Beli, a fọ Merodaki tutu; oju tì awọn ere rẹ̀, a fọ awọn òriṣa rẹ̀ tutu.

3. Nitori lati ariwa ni orilẹ-ède kan ti wá sori rẹ̀, ti yio sọ ilẹ rẹ̀ di ahoro, ẹnikan kì o gbe inu rẹ̀: nwọn o sa, nwọn o lọ, ati enia ati ẹranko.

4. Li ọjọ wọnni ati li àkoko na, li Oluwa wi, awọn ọmọ Israeli yio jumọ wá, awọn, ati awọn ọmọ Juda, nwọn o ma lọ tẹkúntẹkún: nwọn o lọ, nwọn o si ṣafẹri Oluwa Ọlọrun wọn.

5. Nwọn o ma bère ọ̀na Sioni, oju wọn yio si yi sibẹ, nwọn o wá, nwọn o darapọ mọ Oluwa ni majẹmu aiyeraiye, ti a kì yio gbagbe.

6. Awọn enia mi ti jẹ agbo-agutan ti o sọnu: awọn oluṣọ-agutan wọn ti jẹ ki nwọn ṣina, nwọn ti jẹ ki nwọn rìn kiri lori oke: nwọn ti lọ lati ori oke nla de oke kekere, nwọn ti gbagbe ibusun wọn.

7. Gbogbo awọn ti o ri wọn, ti pa wọn jẹ: awọn ọta wọn si wipe, Awa kò jẹbi, nitoripe nwọn ti ṣẹ̀ si Oluwa ibugbe ododo, ati ireti awọn baba wọn, ani Oluwa.

8. Ẹ salọ kuro li ãrin Babeli, ẹ si jade kuro ni ilẹ awọn ara Kaldea, ki ẹ si jẹ bi obukọ niwaju agbo-ẹran.

9. Nitori, wò o, emi o gbe dide, emi o si mu apejọ awọn orilẹ-ède nla lati ilẹ ariwa wá sori Babeli: nwọn o si tẹgun si i, lati ibẹ wá li a o si ti mu u: ọfa wọn yio dabi ti akọni amoye; ọkan kì yio pada li asan.

10. Kaldea yio si di ikogun: gbogbo awọn ti o fi ṣe ikogun ni a o tẹ́ lọrùn, li Oluwa wi.

11. Nitoripe inu nyin dùn, nitoripe ẹnyin yọ̀, ẹnyin olè ti o ji ini mi, nitori ti ẹnyin fi ayọ̀ fò bi ẹgbọrọ malu si koriko tutu, ẹ si nyán bi akọ-ẹṣin:

12. Oju yio tì iya nyin pupọpupọ; itiju yio bo ẹniti o bi nyin: wò o, ikẹhin awọn orilẹ-ède! aginju, ilẹ gbigbẹ, ati ahoro!

13. Nitori ibinu Oluwa li a kì yio gbe inu rẹ̀, ṣugbọn yio dahoro patapata: olukuluku ẹniti o ba re Babeli kọja yio yanu, yio si ṣe ẹlẹya si gbogbo ipọnju rẹ̀.

14. Ẹ tẹgun si Babeli yikakiri: gbogbo ẹnyin ti nfà ọrun, ẹ tafa si i, ẹ máṣe ṣọ́ ọfa lò, nitoriti o ti ṣẹ̀ si Oluwa.

15. Ẹ ho bo o yikakiri: o ti nà ọwọ rẹ̀: ọwọ̀n ìti rẹ̀ ṣubu, a wó odi rẹ̀ lulẹ: nitori igbẹsan Oluwa ni: ẹ gbẹsan lara rẹ̀; gẹgẹ bi o ti ṣe, ẹ ṣe bẹ̃ si i.

16. Ke afunrugbin kuro ni Babeli, ati ẹniti ndi doje mu ni igbà ikore! nitori ẹ̀ru idà ti nṣika, olukuluku wọn o yipada si ọdọ enia rẹ̀, olukuluku yio si salọ si ilẹ rẹ̀.

17. Israeli jẹ́ agutan ti o ṣina kiri, awọn kiniun ti le e lọ: niṣaju ọba Assiria pa a jẹ, ati nikẹhin yi Nebukadnessari, ọba Babeli, sán egungun rẹ̀.

18. Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, wò o, emi o jẹ ọba Babeli ati ilẹ rẹ̀ niya, gẹgẹ bi emi ti jẹ ọba Assiria niya.

Ka pipe ipin Jer 50