Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 41:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe li oṣu keje Iṣmaeli, ọmọ Netaniah ọmọ Eliṣama, ninu iru-ọmọ ọba, ati awọn ijoye ọba, ati ọkunrin mẹwa pẹlu rẹ̀, nwọn tọ̀ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, wá ni Mispa: nibẹ ni nwọn jumọ jẹun ni Mispa.

2. Nigbana ni Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, ati awọn ọkunrin mẹwa ti nwọn wà pẹlu rẹ̀, nwọn fi idà kọlu Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, nwọn si pa a, on ẹniti ọba Babeli ti fi jẹ bãlẹ lori ilẹ na.

3. Pẹlupẹlu Iṣmaeli pa gbogbo awọn ara Juda ti o wà pẹlu rẹ̀, ani pẹlu Gedaliah, ni Mispa, ati awọn ara Kaldea, ti a ri nibẹ, awọn ologun.

4. O si ṣe li ọjọ keji lẹhin ti o ti pa Gedaliah, ti ẹnikan kò si mọ̀.

5. Nigbana ni ọgọrin ọkunrin wá lati Ṣekemu, lati Ṣilo, ati lati Samaria, ti nwọn fá irungbọn wọn, nwọn fà aṣọ wọn ya, nwọn si ṣá ara wọn lọgbẹ, nwọn mu ọrẹ-ẹbọ ati turari li ọwọ wọn lati mu u wá si ile Oluwa.

6. Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, si jade lati Mispa lọ ipade wọn, bi o ti nlọ, o nsọkun: o si ṣe, bi o ti pade wọn, o wi fun wọn pe, jẹ ki a lọ sọdọ Gedaliah, ọmọ Ahikamu.

7. O si ṣe, nigbati nwọn de ãrin ilu, ni Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, pa wọn, on, ati awọn ọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀ si sọ wọn sinu iho.

8. Ṣugbọn ọkunrin mẹwa wà lãrin wọn ti nwọn sọ fun Iṣmaeli pe, máṣe pa wa: nitori awa ni iṣura li oko, ti alikama, ati ti ọka barli, ati ti ororo, ati oyin. Bẹ̃li o jọwọ wọn, kò si pa wọn pẹlu awọn arakunrin wọn.

9. Ati iho na ninu eyi ti Iṣmaeli ti sọ gbogbo okú ọkunrin wọnyi si, awọn ti o ti pa pẹlu Gedaliah, ni eyiti Asa, ọba, ti ṣe nitori ibẹ̀ru Baaṣa, ọba Israeli: Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, si fi awọn ti a pa kún u.

Ka pipe ipin Jer 41