Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 37:4-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Jeremiah si nwọle o si njade lãrin awọn enia: nitori nwọn kò ti ifi i sinu tubu.

5. Ogun Farao si jade lati Egipti wá: nigbati awọn ara Kaldea ti o dótì Jerusalemu si gbọ́ iró wọn, nwọn lọ kuro ni Jerusalemu.

6. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah, woli wá, wipe,

7. Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli wi pe, Bayi li ẹnyin o sọ fun ọba Juda, ti o rán nyin si mi, lati bere lọwọ mi: Wò o, ogun Farao ti o jade lati ràn nyin lọwọ, yio pada si ilẹ rẹ̀, ani Egipti.

8. Awọn ara Kaldea yio si tun wá, nwọn o si ba ilu yi jà, nwọn o kó o, nwọn o si fi iná kún u.

9. Bayi li Oluwa wi; Ẹ máṣe tan ọkàn nyin jẹ, wipe, Ni lilọ awọn ara Kaldea yio lọ kuro lọdọ wa: nitoriti nwọn kì yio lọ.

10. Nitori bi o tilẹ jẹ pe, ẹnyin lu gbogbo ogun awọn ara Kaldea ti mba nyin jà bolẹ, ti o si jẹ pe awọn ọkunrin ti o gbọgbẹ li o kù ninu wọn: sibẹ nwọn o dide, olukuluku ninu agọ rẹ̀, nwọn o si fi iná kun ilu yi.

11. O si ṣe, nigbati ogun awọn ara Kaldea goke lọ kuro ni Jerusalemu nitori ogun Farao,

12. Ni Jeremiah jade kuro ni Jerusalemu lati lọ si ilẹ Benjamini lati pin ini lãrin awọn enia.

13. Nigbati o si wà li ẹnu-bode Benjamini, balogun iṣọ kan wà nibẹ, orukọ ẹniti ijẹ Irijah, ọmọ Ṣelemiah, ọmọ Hananiah; on si mu Jeremiah woli, wipe, Iwọ nsa tọ̀ awọn ara Kaldea lọ.

14. Jeremiah si wipe: Eke! emi kò sa tọ awọn ara Kaldea lọ. Ṣugbọn kò gbọ́ tirẹ̀: bẹ̃ni Irijah mu Jeremiah, o si mu u tọ̀ awọn ijoye wá.

15. Nitorina ni awọn ijoye ṣe binu si Jeremiah, nwọn si lù u, nwọn si fi sinu tubu ni ile Jonatani, akọwe; nitori nwọn ti fi eyi ṣe ile túbu.

16. Bẹ̃ni Jeremiah lọ inu ile-túbu ati inu iyara ṣiṣokunkun. Jeremiah si wà nibẹ li ọjọ pupọ;

17. Nigbana ni Sedekiah, ọba ranṣẹ pè e: ọba si bere lọwọ rẹ̀ nikọkọ ni ile rẹ̀, o si wipe, Ọ̀rọ ha wà lati ọdọ Oluwa? Jeremiah si wipe, O wà: o wi pe, nitori a o fi ọ le ọwọ ọba Babeli.

18. Pẹlupẹlu Jeremiah sọ fun Sedekiah, ọba, pe; Ẹṣẹ wo ni mo ṣẹ̀ ọ, tabi awọn iranṣẹ rẹ, tabi awọn enia yi, ti ẹnyin fi mi sinu ile-túbu?

Ka pipe ipin Jer 37