Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 37:18-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Pẹlupẹlu Jeremiah sọ fun Sedekiah, ọba, pe; Ẹṣẹ wo ni mo ṣẹ̀ ọ, tabi awọn iranṣẹ rẹ, tabi awọn enia yi, ti ẹnyin fi mi sinu ile-túbu?

19. Nibo ni awọn woli nyin ha wà nisisiyi, awọn ti nsọtẹlẹ fun nyin, wipe, Ọba Babeli kì yio wá sọdọ nyin ati si ilẹ yi?

20. Nitorina gbọ́ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, oluwa mi, ọba, jẹ ki ẹ̀bẹ mi, emi bẹ̀ ọ, ki o wá si iwaju rẹ; ki iwọ ki o má jẹ ki emi pada si ile Jonatani akọwe, ki emi má ba kú nibẹ.

21. Sedekiah, ọba, si paṣẹ pe ki nwọn ki o fi Jeremiah pamọ sinu agbala ile-túbu, ati pe ki nwọn ki o ma fun u ni iṣu akara kọ̃kan lojojumọ, lati ita awọn alakara, titi gbogbo akara fi tan ni ilu. Jeremiah si wà li agbala ile-túbu.

Ka pipe ipin Jer 37