Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 36:11-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Nigbati Mikaiah, ọmọ Gemariah, ọmọ Ṣafani, gbọ́ gbogbo ọ̀rọ Oluwa lati inu iwe na wá,

12. O si sọkalẹ lọ si ile ọba, sinu iyara akọwe, si wò o, gbogbo awọn ijoye joko nibẹ, Eliṣama, akọwe, ati Delaiah, ọmọ Semaiah, ati Elnatani, ọmọ Akbori, ati Gemariah, ọmọ Safani, ati Sedekiah, ọmọ Hananiah, ati gbogbo awọn ijoye.

13. Nigbana ni Mikaiah sọ gbogbo ọ̀rọ wọnni ti o ti gbọ́, fun wọn, nigbati Baruku kà lati inu iwe na li eti awọn enia.

14. Nigbana ni gbogbo awọn ìjoye rán Jehudu, ọmọ Netaniah, ọmọ Ṣelemiah, ọmọ Kuṣi, si Baruku wipe, Mu iwe-kiká na li ọwọ rẹ, lati inu eyiti iwọ kà li eti awọn enia, ki o si wá. Nigbana ni Baruku, ọmọ Neriah, mu iwe-kiká na li ọwọ rẹ̀, o si wá si ọdọ wọn.

15. Nwọn si wi fun u pe, Joko nisisiyi, ki o si kà a li eti wa. Baruku si kà a li eti wọn.

16. Njẹ, o si ṣe, nigbati nwọn gbọ́ gbogbo ọ̀rọ na, nwọn warìri, ẹnikini si ẹnikeji rẹ̀, nwọn si wi fun Baruku pe, Awa kò le ṣe aisọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun ọba.

17. Nwọn si bi Baruku wipe, Sọ fun wa nisisiyi, bawo ni iwọ ṣe kọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi lati ẹnu rẹ̀?

18. Baruku si da wọn lohùn pe; Lati ẹnu rẹ̀ li o si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun mi, emi si fi tadawa kọ wọn sinu iwe na.

19. Nigbana ni awọn ijoye sọ fun Baruku pe, Lọ, fi ara rẹ pamọ, iwọ ati Jeremiah; má si jẹ ki ẹnikan mọ̀ ibi ti ẹnyin wà.

20. Nwọn si wọle tọ̀ ọba lọ ninu àgbala, ṣugbọn nwọn fi iwe-kiká na pamọ si iyara Eliṣama, akọwe, nwọn si sọ gbogbo ọ̀rọ na li eti ọba.

Ka pipe ipin Jer 36