Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 36:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe li ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah ọba Juda, li ọ̀rọ yi tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa wá, wipe,

2. Mu iwe-kiká fun ara rẹ̀, ki o si kọ sinu rẹ̀, gbogbo ọ̀rọ ti emi ti sọ si Israeli, ati si Juda, ati si gbogbo orilẹ-ède, lati ọjọ ti mo ti sọ fun ọ, lati ọjọ Josiah titi di oni yi.

3. O le jẹ pe ile Juda yio gbọ́ gbogbo ibi ti mo pinnu lati ṣe si wọn; ki nwọn ki o le yipada, olukuluku kuro li ọ̀na buburu rẹ̀; ki emi ki o dari aiṣedede wọn ati ẹ̀ṣẹ wọn ji wọn.

4. Nigbana ni Jeremiah pè Baruku, ọmọ Neriah; Baruku si kọ lati ẹnu Jeremiah gbogbo ọ̀rọ Oluwa ti o ti sọ fun u, sori iwe-kiká na.

5. Jeremiah si paṣẹ fun Baruku pe, a se mi mọ: emi kò le lọ si ile Oluwa:

6. Nitorina iwọ lọ, ki o si kà ninu iwe-kika na, ti iwọ kọ lati ẹnu mi wá, ọ̀rọ Oluwa li eti awọn enia ni ile Oluwa li ọjọ ãwẹ: ati pẹlu, iwọ o si kà a li eti gbogbo Juda, ti nwọn jade wá lati ilu wọn.

7. O le jẹ pe, ẹ̀bẹ wọn yio wá siwaju Oluwa, nwọn o si yipada, olukuluku kuro li ọ̀na buburu rẹ̀: nitoripe nla ni ibinu ati irunu ti Oluwa ti sọ si awọn enia yi.

8. Baruku, ọmọ Neriah, si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jeremiah, woli, ti palaṣẹ fun u, lati ka ọ̀rọ Oluwa lati inu iwe ni ile Oluwa.

9. O si ṣe li ọdun karun Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, li oṣu kẹsan ni nwọn kede ãwẹ niwaju Oluwa, fun gbogbo enia ni Jerusalemu: ati fun gbogbo awọn enia ti o wá lati ilu Juda, si Jerusalemu.

10. Baruku si ka ọ̀rọ Jeremiah lati inu iwe ni ile Oluwa, ni iyara Gemariah, ọmọ Ṣafani, akọwe, ni àgbala oke, nibi ilẹkun ẹnu-ọ̀na titun ile Oluwa li eti gbogbo enia.

11. Nigbati Mikaiah, ọmọ Gemariah, ọmọ Ṣafani, gbọ́ gbogbo ọ̀rọ Oluwa lati inu iwe na wá,

Ka pipe ipin Jer 36