O si ṣe li ọdun karun Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, li oṣu kẹsan ni nwọn kede ãwẹ niwaju Oluwa, fun gbogbo enia ni Jerusalemu: ati fun gbogbo awọn enia ti o wá lati ilu Juda, si Jerusalemu.