Jeremiah si wi fun ile awọn ọmọ Rekabu pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Nitori ti ẹnyin gbà ofin Jonadabu, baba nyin gbọ́, ti ẹnyin si pa gbogbo ilana rẹ̀ mọ, ti ẹ si ṣe gẹgẹ bi eyi ti o ti palaṣẹ fun nyin: