Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 35:15-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Emi si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ mi, awọn woli, si nyin pẹlu, emi dide ni kutukutu, mo ran wọn wipe, Ẹ yipada nisisiyi, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ki ẹ si tun iṣe nyin ṣe rere, ki ẹ máṣe tọ̀ awọn ọlọrun miran lẹhin lati sin wọn, ẹnyin o si ma gbe ilẹ na ti mo ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin; ṣugbọn ẹnyin kò tẹ eti nyin, bẹ̃ni ẹnyin kò si gbọ́ temi.

16. Lõtọ awọn ọmọ Jonadabu, ọmọ Rekabu, pa ofin baba wọn mọ, ti o pa laṣẹ fun wọn; ṣugbọn awọn enia yi kò gbọ́ ti emi:

17. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi pe, Wò o, emi o mu wá sori Juda, ati sori gbogbo olugbe Jerusalemu, gbogbo ibi ti emi ti sọ si wọn; nitori ti emi ti ba wọn sọ̀rọ, nwọn kò si gbọ́; mo si ti pè wọn, nwọn kò si dahùn.

18. Jeremiah si wi fun ile awọn ọmọ Rekabu pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Nitori ti ẹnyin gbà ofin Jonadabu, baba nyin gbọ́, ti ẹnyin si pa gbogbo ilana rẹ̀ mọ, ti ẹ si ṣe gẹgẹ bi eyi ti o ti palaṣẹ fun nyin:

19. Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Jonadabu, ọmọ Rekabu kì yio fẹ ọkunrin kan kù lati duro niwaju mi lailai.

Ka pipe ipin Jer 35