Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 32:33-44 Yorùbá Bibeli (YCE)

33. Nwọn si ti yi ẹhin wọn pada si mi, kì isi ṣe oju: emi kọ́ wọn, mo ndide ni kutukutu lati kọ́ wọn, sibẹ nwọn kò fetisilẹ lati gbà ẹkọ.

34. Nwọn si gbe ohun irira wọn ka inu ile na, ti a fi orukọ mi pè, lati sọ ọ di aimọ́.

35. Nwọn si kọ́ ibi giga Baali, ti o wà ni afonifoji ọmọ Hinnomu, lati fi awọn ọmọkunrin wọn ati awọn ọmọbinrin wọn fun Moleki; ti emi kò paṣẹ fun wọn, bẹ̃ni kò wá si ọkàn mi, pe ki nwọn ki o mã ṣe ohun irira yi, lati mu Juda ṣẹ̀.

36. Njẹ nisisiyi, bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niti ilu yi, sipa eyiti ẹnyin wipe, A o fi le ọwọ ọba Babeli, nipa idà, ati nipa ìyan, ati nipa ajakalẹ-arun.

37. Wò o, emi o kó wọn jọ lati gbogbo ilẹ jade, nibiti emi ti le wọn si ninu ibinu mi, ati ninu irunu mi, ati ninu ikannu nla; emi o si jẹ ki nwọn ki o mã gbe lailewu:

38. Nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn.

39. Emi o si fun wọn li ọkàn kan, ati ọ̀na kan, ki nwọn ki o le bẹ̀ru mi li ọjọ gbogbo, fun rere wọn, ati ti awọn ọmọ wọn lẹhin wọn:

40. Emi o si ba wọn dá majẹmu aiyeraiye, pe emi kì o yipada lẹhin wọn lati ṣe wọn ni rere, emi o fi ibẹ̀ru mi si ọkàn wọn, ti nwọn kì o lọ kuro lọdọ mi.

41. Lõtọ, emi o yọ̀ lori wọn lati ṣe wọn ni rere, emi o si gbìn wọn si ilẹ yi li otitọ tinutinu mi ati tọkàntọkàn mi.

42. Nitori bayi li Oluwa wi; Gẹgẹ bi emi ti mu gbogbo ibi nla yi wá sori awọn enia yi, bẹ̃ni emi o mu gbogbo rere ti emi ti sọ nipa ti wọn wá sori wọn.

43. Enia o si rà oko ni ilẹ yi, nipa eyi ti ẹnyin wipe, Ahoro ni laisi enia, laisi ẹran, a fi le ọwọ awọn ara Kaldea.

44. Enia yio fi owo rà oko, nwọn o kọ ọ sinu iwe, nwọn o si dí i, nwọn o si pe awọn ẹlẹri ni ilẹ Benjamini, ati ni ibi wọnni yi Jerusalemu ka, ati ni ilu Juda, ati ni ilu ọwọ́-oke na, ati ni ilu afonifoji, ati ni ilu iha gusu; nitori emi o mu igbekun wọn pada wá, li Oluwa wi.

Ka pipe ipin Jer 32